Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Oludije sipo alaga kansu nijọba ibilẹ Ọffa, ninu ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP), nibi eto idibo ijọba ibilẹ to waye nipinlẹ Kwara, lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹsan-an, ọdun yii, Salaudeen Lukman, ti ni eto idibo kankan ko waye niluu Ọffa, rara.
Ninu atẹjade kan ti oludije ọhun fi sita laṣaalẹ ọjọ Abamẹta, Satide, lo ti ni eto idibo kankan ko waye niluu Ọffa, latari awọn aiṣedeedee kan to waye.
Bakan naa lo bu ẹnu atẹ lu ajọ eleto idibo ni Kwara, Kwara State Independent Electoral Commission (KWASIEC), lori bi wọn ṣe kuna lati tete gbe awọn eroja idibo lọ sawọn ibudo idibo yika-yika ipinlẹ naa. O ni lẹyin ti ajọ naa ti kede pe aago mẹjọ aarọ ni idibo yoo bẹrẹ, titi to fi di aago kan ọsan, wọn o gbe awọn eroja idibo lọ ṣawọn ibudo idibo, leyi ti ko bojumu. O ni fun idi eyi, ẹgbẹ oṣelu PDP atawọn t’ọrọ kan n fi asiko naa ke si gbogbo aye pe eto idibo ko waye niluu Ọffa.
Ni igunlẹ ọrọ rẹ, Lukman waa rọ ajọ eleto idibo ki wọn mu ọjọ miiran ọjọ ire ti eto idibo mi-in yoo waye, ni eyi ti ko ni i ni magomago kankan ninu.