Faith Adebọla
Ka kẹru, ka kẹru wale lọdẹ n ba lọ soju ogun, ọna nikẹta n ba wọn, ohun tawọn eeyan ko reti ti n ṣẹlẹ bi eto idibo sipo gomina ati awọn aṣofin ipinlẹ ṣe ku wakati perete ti yoo bẹrẹ yii, ibo ọhun ku wakati mẹrinlelogun pere ni wọn ji oludije sipo igbakeji gomina ipinlẹ Calabar labẹ ẹgbẹ oṣelu Young Progressives Party, YPP, Ọmọọba Agbor Onyi, gbe, afaimọ ni ki i ṣe akata awọn ajinigbe naa lọkunrin ọhun yoo wa titi teto idibo ọhun yoo fi kọja.
Alaroye gbọ pe yatọ si oludije yii, wọn tun ji awọn mẹta mi-in pẹlu rẹ lasiko tawọn afurasi agbebọn kan lọọ rẹbuu ọkọ Toyota Corolla wọn lọna lọsan-an l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹta yii, awọn mẹta ọhun ni Igbakeji ọga agba fun ileeṣẹ to n ri si iwọle-wọde nilẹ wa, iyẹn Nigeria Immigration Service, ASI Imojara Godwin, Abilekọ Sandra Egbung Odama ati ẹnikan ti wọn porukọ ẹ ni Walter.
Nnkan bii aago mẹta aabọ irọlẹ ọjọ niṣẹlẹ buruku naa waye, lasiko tawọn eeyan yii n lọ si iha Ariwa ipinlẹ Cross River, ibi kan ti wọn n pe ni Biase, lọna Calabar, si Ogoja ni wọn ti ji wọn gbe.
Wọn ni nitori kawọn eeyan yii le lọọ kopa ninu eto idibo naa lagbegbe ti kaluku wọn ti forukọ silẹ ni wọn ṣe rinrin-ajo ọhun.
Ẹnikan to ba awọn oniroyin sọrọ, ṣugbọn ti ko fẹ ki wọn darukọ oun sọ pe ni nnkan bii aago meje aabọ alẹ ọjọ naa, awọn ajinigbe naa ti pe awọn mọlẹbi awọn ti wọn ji gbe lori aago, wọn ni ki wọn lọọ wa miliọnu lọna ọgọta Naira (N60 million) wa, kawọn le tu awọn ẹni wọn ti mu londe silẹ, amọ nigba to ya, wọn lawọn yoo gba miliọnu lọna ogoji.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Cross Rivers, SP Irene Ugbo, ti fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, o lawọn ti n sapa lati tọpasẹ awọn ajinigbe naa, iṣẹ iwadii si ti n lọ labẹnu lojuna bi wọn ṣe maa ri awọn ti wọn ji gbe naa gba pada laaye, lai sewu.
“Kọmiṣanna ọlọpaa ti paṣẹ fawọn agbofinro atawọn ọtẹlẹmuyẹ lati bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ yii, a gbagbọ pe ki ibo too bẹrẹ lọjọ Satide, wọn yoo ti gba ominira,” gẹgẹ bo ṣe wi.
Amọ titi dasiko ta a fi n ko iroyin yii jọ, awọn ajinigbe naa ko ti i tu wọn silẹ.