Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Gomina ipinlẹ Ọṣun, Ademọla Adeleke, ti sọ pe idajọ ti ko lẹsẹ nilẹ ni eyi ti igbimọ to gbọ ẹsun to su yọ ninu eto idibo ipinlẹ naa to waye lọdun to kọja da. O ni oun yoo pe ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun lori idajọ yii.
Nigba to n sọrọ lori idajọ to gba ipo lọwọ rẹ ọhun, Akọwe iroyin Adeleke to sọrọ lorukọ gomina, Ọlawale Rasheed, sọ pe ibo adiju ti ile-ẹjọ naa gbe idajọ wọn le lori ti wọn fi ni Oyetọla lo bori lodi si ifẹ inu awọn oludibo ti wọn dibo wọn lọpọ yanturu fun oun.
Adeleke waa fọkan awọn ololufẹ rẹ balẹ, o ni ki wọn ma ṣe bẹru, bẹẹ ni ki wọn ma foya, nitori oun yoo pe ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun ta ko idajọ naa. O fi kun un pe oun ṣi ni gomina ipinlẹ Ọṣun, ko si si ohunkohun to le yọ ohun nipo naa, nitori awọn araalu ni wọn fi ibo gbe oun wọle.
Adeleke ni, ‘‘Mo fẹẹ rọ ẹyin eeyan mi pe ki ẹ ni suru, a maa pe ẹjọ ta ko idajọ naa, mo si gbagbọ pe idajọ ododo yoo tẹ wa lọwọ. Mo fi n da ẹyin eeyan mi loju pe gbogbo ohun to ba yẹ lati ṣe ni a maa ṣe lati ri i pe ifẹ inu awọn eeyan ti wọn fi ibo yan wa ko bọ sọnu’’.
Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kin-in-ni, ọdun yii, ni olori igbimọ to n gbọ ẹjọ to su yọ lasiko idibo, Onidaajọ Tetsea Kume, sọ nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ pe ajọ eleto idibo ko tẹle ilana ati ofin ti orileede wa n tẹle lori eto idibo, bakan naa ni wọn ṣe lodi sofin eto idbo ti wọn ṣatunṣe si.
Igbimọ naa ni leyin ti awọn yọ adiju ibo, Oyetọla ni ibo ẹgbẹrun lọna ọọdunrun o le mẹrinla ati diẹ, nigba ti Adeleke ni ibo ọọdunrun din mẹwaa ati diẹ (290,266).
Tẹ o ba gbagbe, ni kete ti wọn kede Adeleke gẹgẹ bii ẹni to jawe olubori ninu idibo to waye lọjọ kẹrindinlogun, oṣu Keje, ọdun to kọja ni Oyetọla ati ẹgbẹ APC ti gba kootu lọ, ti wọn ni adiju ibo waye lawọn ibi kan, ati pe Adeleke ko ni iwe-ẹri to kunju oṣuwọn lati dupo gomina l’Ọṣun, wọn ni ayederu ni iwe-ẹri to ni.
Bo tilẹ jẹ pe ile-ẹjọ wẹ Adeleke mọ lori ọrọ iwe-ẹri, ọkunrin ọmọ bibi ilu Ẹdẹ naa ko le mori bọ nibi ọrọ adiju ibo.