Ibo Ọṣun: Ile idibo mẹfa pere ni mo ti ri adiju ibo – Ọduntan

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Akọṣẹmọṣẹ kan nipa iwadii ohun to ba ruju (Forensic Expert and Statistician), Samuel Ọduntan, ẹni ti Gomina Adeleke pe lati jẹrii lori awọn ẹsun ti gomina ana, Adegboyega Oyetọla, fi kan ijawe olubori rẹ ti sọ pe ile idibo mẹfa pere loun ti ri i pe adiju ibo ti waye.

Bakan naa ni ẹlẹrii Adeleke miiran tun ko awọn risọọti ti gomina naa gba nile ẹkọ giga kan lorileede United States wa si kootu pẹlu aworan oriṣii mẹsan-an to ya pẹlu aṣọ ikẹkọọ-jade.

A oo ranti pe esi idibo ile idibo ọtalelẹẹẹdẹgbẹrin o din mọkanla (749)  kaakiri ijọba ibilẹ mẹwaa nipinlẹ Ọṣun, ni Oyetọla ati ẹgbẹ APC gbe lọ siwaju igbimọ olugbẹjọ pe idibo ibẹ ko si nibaamu pẹlu alakalẹ ofin eto idibo orileede yii.

Nigba ti agbẹjọro Adeleke, Onyechi Ikpeazu (SAN), n beere ọrọ lọwọ Ọduntan, o ni oun ṣayẹwo ẹrọ BIVAS ti ajọ eleto idibo INEC ko fun un, oun si yannana wọn pẹlu awọn Fọọmu EC8.

O ni lara awọn ile idibo ọtalelẹẹdẹgbẹrin toun ṣayẹwo nibẹ, ile idibo mẹfa pere loun ti ṣakiyesi pe adiju ibo ti waye. O ni bo tilẹ jẹ pe iṣẹ ti wọn gba oun fun, ti oun si gbowo lori rẹ loun n ṣe, sibẹ, eyi ko ni nnkan kan an ṣe pẹlu akọsilẹ awọn nnkan ti oun ri.

Lasiko ti agbẹjọro awọn olujẹjọ, Akin Olujinmi (SAN), n beere ibeere lọwọ rẹ, Ọduntan sọ pe oun ki i ṣe alakooso idibo naa, bẹẹ ni oun ko lo ẹrọ BIVAS kankan lasiko idibo ọhun.

O gba pe ni oju-iwe kẹẹẹdọgbọn ti akọsilẹ ile idibo keje ni Wọọdu kẹrin tijọba ibilẹ Guusu Ẹdẹ wa, iye awọn oludibo jẹ okoolelọọọdunrun o din meje, ṣugbọn ninu akọsilẹ ẹri rẹ, ọrinlelọọọdunrun o le mẹjọ lo wa nibẹ.

Bakan naa ni Oluranlọwọ pataki fun Adeleke, Samuel Bunmi-Jẹnyọ, ko awọn risọọti ti Adeleke gba lati Atlanta Metropolitan College atawọn fọto to ya nibẹ wa si kootu.

O sọ ninu ẹri rẹ pe ko sigba kankan ti wọn fi ẹsun yiyi iwe kan Adeleke ri.

Lẹyin atotonu abala mejeeji ni alaga igbimọ olugbẹjọ naa, Onidaajọ Tertsea Kume, sun igbẹjọ si ọjọ kẹtala, oṣu Kin-in-ni, ọdun 2023, lati le jẹ ki abala mejeeji fọwọ si akọsilẹ wọn (Adoption of the final written addresses)

Leave a Reply