Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Lẹyin ti agbejọro olupẹjọ ati tawọn olujẹjọ ti gbe akọsilẹ ẹjọ wọn siwaju ile-ẹjọ to n gbọ ẹsun to ṣu yọ ninu idibo gomina ipinlẹ Ọṣun loṣu Keje, ọdun 2022, ile-ẹjọ ti sọ pe gbogbo wọn yoo gbọ ọjọ idajọ laipẹ.
Ninu ariyanjiyan awọn abala mejeeji nile-ẹjọ, agbẹjọro fun olujẹjọ akọkọ, Ọjọgbọn Paul Ananaba, SAN, sọ pe loootọ ni awọn kudiẹ-kudiẹ wa ninu akọsilẹ ile idibo ẹgbẹsan o din diẹ (1750), ṣugbọn bi wọn ba yọ ọ kuro ninu esi idibo to wa nilẹ, sibẹ, onibaara oun yoo jawe olubori.
O ni, “Ṣe ni olupẹjọ kan yọ ile idibo ọtalelẹẹẹdẹgbẹrin o din mọkanla lati le ri nnkan ti wọn fẹ. Ti a ba duro lori ẹṣibiiti BVR, ti a ba yọ ile idibo ẹgbẹsan o din diẹ kuro ninu ile idibo ẹgbẹrun mẹrin o din diẹ (3763) to ni i ṣe pẹlu ẹgbẹ oṣelu mejeeji, olujẹjọ keji yoo jawe olubori pẹlu ibo ẹgbẹrun lọna ogun”
Agbẹjọro olupẹjọ, Lateef Fagbemi SAN, sọ pe aṣiṣe nla gbaa ni ajọ eleto idibo (INEC) ṣe lati gbe ẹda meji akọsilẹ (Certified True Copy) jade, ki wọn tun too waa maa sọ nigbẹyin pe abọ akọsilẹ ni ọkan.
Fagbemi ṣalaye pe ofin idibo tuntun ko mọ nnkan to n jẹ aabọ akọsilẹ (Synchronized report), o ni ti ajọ INEC ba jẹ lọ lori eleyii, o tumọ si pe wọn kan le deede kede esi idibo lọjọ kan, ti wọn yoo si tun sọ lọjọ keji pe ki i ṣe akọsilẹ to peye lawọn gbe jade.
“Ọrọ esi idibo yatọ si iforukọsilẹ. Ohun to tọ ni sisọ bi esi idibo ba ṣe n wọle, ki i ṣe ṣiṣe afikun iye awọn ti wọn forukọsilẹ.”
O fi kun ọrọ rẹ pe oluwọle ni iwe-ẹri ti olujẹjọ keji, iyẹn Gomina Ademọla Adeleke, fi kalẹ ni kootu, nitori ọdun 1988 lo wa nibẹ pe o gba tẹstimonia rẹ, ko too di pe wọn ṣe idasilẹ Ọṣun lọdun 1991, o si ke si kootu lati fagi le igbesẹ ti wọn fi kede rẹ gẹgẹ bii ẹni to jawe olubori ninu idibo naa.
Ni tiẹ, agbẹjọro fun olujẹjọ keji, Onyechi Ikpeazu (SAN), ni ọna ti wọn le gba lati sọ pe adiju ibo wa ni nipasẹ akọsilẹ awọn oludibo, akọsilẹ BVR ati akọsilẹ Form EC8A, ko si si eyikeyii ninu mẹtẹẹta to fidi eyi mulẹ.
O ni olupẹjọ ko pe ẹlẹrii kankan lati fidi rẹ mulẹ pe ayederu ni iwe-ẹri ti olujẹjọ fi silẹ fun ajọ INEC, bẹẹ ni ko pe ẹlẹrii kankan lati ileewe naa.
Ikpeazu sọ siwaju pe awọn ti ṣe aropọ adiju ibo to wa ni ile idibo mẹfa pere, ẹgbẹ PDP ni ẹgbẹfa ibo, nigba ti ẹgbẹ APC ni ibo ẹẹdẹgbẹrin.
Agbẹjọro fun olujẹjọ kẹta (PDP), Alex Izinyon (SAN) sọ pe ọrọ Ẹdẹ Muslim High School, ati Grammar School, ti yanju, nitori ọga agba ileewe naa ti sọ pe orukọ ileewe kan naa ni mejeeji.
Lẹyin atotonu abala mejeeji ni alaga igbimọ olugbẹjọ naa, Onidaajọ Tertsea Kume, sọ pe gbogbo wọn yoo gbọ ọjọ idajọ laipẹ.