Ibo ọdun 2027: Ko saaye rara fun Atiku – Wike 

Adewale Adeoye

Minisita ilu Abuja, to tun jẹ ọkan pataki lara awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP, Ọgbẹni Nysome Wike, ti sọ pe ko saaye kankan fun Alhaji Atiku Abubakar lati jide dupo aarẹ orileede yii lorukọ ẹgbẹ oṣelu PDP lọdun 2027 rara mọ, nitori pe awọn araalu ko nifẹẹ si i mọ, wọn ko si ni i faaye gba a rara lati dije dupo naa mọ labẹ ẹgbẹ PDP.

Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹtala, oṣu Kọkanla, ọdun yii, ni Wike sọrọ ọhun di mimọ nibi eto pataki kan to waye niluu Abuja. O ni aimọye igba ni Alhaji Atiku Abubakar ti sọ erongba rẹ fawọn araalu bo ba wọle sipo aarẹ orileede yii, ti wọn si ti fibo wọn soro fun un pe awọn ko nifẹẹ si i rara.

Bẹẹ o ba gbagbe, ọsẹ to kọja yii ni Alhaji Atiku Abubakar sọ pe bo ba jẹ oun loun wa nipo aarẹ orileede yii ni, aimọye nnkan loun maa ṣe lọna to yatọ gedengbe si bi Aarẹ Tinubu ti n ṣe e yii, nitori pe iṣakooso to wa nibẹ bayii n febi pa araalu gidi ni.

Ni idahun sọrọ ti Atiku sọ yii lo mu ki Wike naa fi sọ pe, ‘Ṣebi o sọ ohun to o maa ṣe fawọn araalu lasiko ipolongo ibo rẹ, ki lo de tawọn araalu ko ṣe dibo wọn fun ẹ. O tun fẹẹ dọgbọn mi-in lo ṣe n sọ awọn ohun ti o n sọ yii. Ko saaye fun ẹ mọ, awọn araalu ko nifẹẹ si ẹ mọ rara, igba meloo gan-an lo fẹẹ dupo naa bayii’’.

Leave a Reply