Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Nigba ti yoo ba fi di oṣu kejila, ọdun yii, gbogbo wahala ati idaamu ti awọn eeyan ti wọn n gba ọna Eko si Sango-Ọta, nipinlẹ Ogun, n koju yoo ti dohun igbagbe, nitori iṣẹ atunṣe yoo bẹrẹ loju ọna naa laipẹ gẹgẹ bi Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun, ṣe wi.
Ki i ṣe ọna yii nikan, bakan naa niṣẹ yoo ṣe bẹrẹ loju ọna Eko si Idiroko naa.
Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu kẹsan-an yii, ni Abiọdun sọ eyi di mimọ lasiko to n mu Minisita Iṣẹ-ode ati ile kikọ lorilẹ-ede yii, Ọgbẹni Babatunde Raji Fashọla, kaakiri lati ṣayẹwo si ibi kan ti wọn n pe ni Toll Plaza, ti iṣẹ n lọ lori rẹ lọwọ lagbegbe Lotto, loju ọna marosẹ Eko s’Ibadan.
Gomina ṣalaye pe atunṣe awọn ọna yii yoo waye lati ọwọ ajọ to tun ọna ṣe ti wọn n pe ni FERMA. O ni yoo le ṣẹnji diẹ ni biliọnu mẹtala ti wọn yoo fi ṣe e(13.4b), eyi yoo si jẹ ara biliọnu mẹrindinlọgọta (56b) ti wọn ya sọtọ fun iṣẹ ọna yii.
“A maa ko awọn to n taja lawọn ọna yii kuro lọ sibomi-in, a maa ri si sun-kẹrẹ fa-kẹrẹ ọkọ to maa n ṣẹlẹ nibẹ, gbogbo ohun to ba yẹ ka ṣe pata la maa ṣe lati mu idẹrun ba awọn eeyan to n gba oju ọna yii lojumọ.
“Ipo ti ọna yii wa bayii ṣeeyan laaanu pupọ, emi naa gba ibẹ kọja, aanu awọn eeyan ilu yii si ṣe mi, ṣugbọn gẹgẹ bi minista ṣe sọ, a maa tete wa atunṣe si awọn apa ibi to ti bajẹ gidi loju ọna yii, ki i ṣe ni Tool Gate nikan, ṣugbọn titi de bii kilomota meji si i loju ọna yii, titi de Abẹokuta ni” Bẹẹ ni Gomina Dapọ Abiọdun wi.
Nipa ti Ọta-Idiroko, o ni wọn ko ti i gbe e fun agbaṣẹṣe kankan fun atunṣe, ṣugbọn oun ti ba Ọtunba Mike Adenuga sọrọ, pe ko fi owo-ori ti ileeṣẹ rẹ iba san ṣe ọna naa gẹgẹ bii ọna ibaṣepọ pẹlu ijọba. Gomina sọ pe eyi ko yatọ si bi Dangote ṣe n fi owo ori ileeṣẹ rẹ ṣe ọna Interchange si Papalanto. Gomina ni bawọn ko ba ṣe ohun to yẹ ni, Dangote ko ni i fi owo rẹ ṣe ọna yii, nitori o fẹrẹ to aadọrin biliọnu (70b) ti atunṣe ọna nla meji naa yoo na an. Bakan naa lo ni Dangote tun ti gba lati ṣe ọna Ẹpẹ-Ijẹbu-Ode lati Odogbolu.
Ninu ọrọ Minista to ṣabẹwo sipinlẹ Ogun naa, Babatunde Fashọla, o ni oju ọna Eko si Ọta yii, ọwọ ijọba ana lawọn ti jogun ẹ. Fashọla sọ pe ọdun 2000 ni wọn kọkọ gbe e fun agbaṣẹṣe, biliọnu mẹfa naira ni wọn ni ki wọn fi ṣe e nigba naa, ṣugbọn ni bayii, biliọnu mẹrindinlọgọta (56b) ni ọna yii yoo nilo ko too pari patapata.
O ni loootọ lo jẹ pe wọn pari ọna naa lapa ibi ti Eko pari si, keeyan too wọ ipinlẹ Ogun, o ni ṣugbọn ibi ati-gun oke biriji Ọta ko bọ si i rara.
Nipa ti Ọta-Idiroko, Fashọla sọ pe iṣẹ ti n lọ lori wiwọn ọna yii ati bawọn yoo ṣe ṣe e. O ni ijọba ipinlẹ Ogun naa si ti ṣetan lati ṣe koto idaminu, ki wọn si palẹ ohun gbogbo to ba yẹ mọ lọna yii.
Minista yii kaaanu awọn to n gba ọna yii, o ni ijọba paapaa nilo atilẹyin awọn aṣofin, nipa titete yọnda owo fawọn iṣẹ idagbasoke bii eyi lorilẹ-ede wa.