Jọkẹ Amọri
Ọkan pataki ninu awọn aṣaaju awọn eeyan ẹya Ijaw, Niger Delta, Edwin Clark, ti sọ pe labẹ akoso bo ṣe wu ko ri, oun ko ni i dibo oun fun Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu to n gbero lati di aare ilẹ Naijiria. O ni kaka bẹẹ, Igbakeji Aarẹ ilẹ wa, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo, loun maa dibo fun. O ni Tinubu ti dagba, o ṣi gba ọkunrin naa niyanju pe ko lọ sile ko lọọ sinmi, ko gbagbe erongba lati di aarẹ ilẹ wa.
Baba agbalagba yii sọrọ naa nigba ti ileesẹ tẹlifiṣan kan, Arise TV, gba a lalejo l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ to kọja.
Clark ṣapejuwe Ọṣinbajo gẹgẹ bii eni to ni ọpọlọ, to si ni gbogbo amuyẹ to to lati dari Naijiria bo ba di aarẹ lọdun 2023.
Clark ni, ‘‘Ilẹ Yoruba jẹ ọkan ninu awọn agbegbe ti awọn to gbajumọ, to si kawe daadaa pọ si ju lọ, ṣugbọn pẹlu rẹ naa, ki Tinubu lọọ sinmi. Ta a ba ti yọwọ eeyan mi-in lati ilẹ Ibo, Ọṣinbajo ni ma a dibo mi fun, nitori o ni oye lori daadaa.
‘‘Ẹẹmeloo la ti gbọ ti Tinubu sọrọ nipa bi nnkan ṣe n lọ lorileede yii ati ọna ti ko daa ti awọn adari wa n gba ṣakoso ilẹ wa.
Gomina Eko tẹlẹ naa sọ pe oun ti ṣọ fun Aarẹ Buhari pe oun fẹẹ di aarẹ Naijria nitori ifẹ ọkan ohun lati ọjọ pipẹ ni.
Bo tilẹ jẹ pe Igbakeji Aarẹ ilẹ wa, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo, ko ti i jade lati sọ pe oun fẹẹ dupo aarẹ, awọn eeyan gbagbọ pe ọkunrin naa yoo pada jade lati ṣe bẹẹ, nitori ọpọlọpọ awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ ni wọn ti n rọ ọ pe ko waa dupo naa, ko le lo iriri ati ọgbọn isakoso rẹ lati tun orileede yii ṣe.