Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Yatọ si bo ṣe ṣẹlẹ lasiko ibo aarẹ to waye kọja, awọn oludibo ko jade daadaa lati dibo niluu Oṣogbo.
Ni gbogbo wọọdu ti akọroyin wa de niluu Oṣogbo, ko si ero pupọ lori ila titi di nnkan bii aago mẹsan-an owurọ.
Ẹnikan to ba wa sọrọ ni Yuniiti kẹfa, Wọọdu 3, nijọba ibilẹ Oṣogbo, Ọgbẹni Baruwa, o ni ohun to fa a ti awọn eeyan ko ṣe fi gbogbo ara jade fun idibo oni ni pe iyatọ ti ba eto idibo ilẹ wa.
O ni gbogbo wọn ni wọn ti gbagbọ pe ko si oloṣelu ti yóò fun awọn ni owo bo ṣe maa n ṣẹlẹ tẹlẹ, idi niyẹn ti wọn fi jokoo sile.
O ni awọn oludibo ti wọn mọ nnkan ti wọn n ṣe, ti wọn si nigbagbọ ninu eto ijọba-awa-wa-ra ilẹ wa nikan ni wọn jade fun idibo oni.