Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Igbadun iṣẹju diẹ, yunkẹyunkẹ takọ-tabo ẹẹkan ṣoṣo ti ṣakoba fawọn ọkunrin meji kan, Idowu Yahaya ati John Balogun, akolo ajọ ṣifu difẹnsi, ẹka tipinlẹ Kwara, ni wọn ti n ṣẹju pako bayii, ẹsun ifipa ba ni lo pọ ni wọn fi kan wọn.
L’Ọjọruu, Wẹsidee, ogunjọ, oṣu Kẹjọ yii, ni ọga ajọ ṣifu difẹnsi nipinlẹ Kwara, Umar J. G Mohammed, safihan awọn afurasi mejeeji naa lolu ileeṣẹ wọn to wa lagbegbe Post office, niluu Ilọrin. O ni Idowu Yahaya, ẹni ọdun mọkandinlọgbọn (39), ati John Balogun, ẹni ọdun mọkandinlaaadọta (49), ni ọwọ tẹ fẹsun ifipabanilopọ ti wọn fi kan wọn.
O tẹsiwaju pe Idowu Yahaya to jẹ ọdẹ aṣọle lọwọ tẹ fẹsun pe o fipa ba ọmọbinrin ẹni ẹdun mẹẹẹdogun kan lasepọ lọfiiṣi rẹ to wa lagbegbe Gàá-Àkàǹbí, niluu Ilọrin. Bakan naa ni ọwọ tẹ Balogun John, to n ṣiṣẹ olukọ nileewe girama alaadani kan fẹsun pe o fipa ba ẹni ọdun mẹtadinlogun kan lo pọ lagbegbe Òséré, niluu Ilọrin, ti wọn si ti wa lakolo awọn bayii. O ni lẹyin ẹkunrẹrẹ iwadii lawọn yoo foju wọn ba Ile-ẹjọ.
O rọ awọn obi ati alagbatọ lati maa mojuto awọn ọmọ wọn, ki wọn si jẹ ki awọn ọmọ wọn maa wa lakata wọn nigbagbogbo ki irufẹ ifipa ba awọn ọmọde lo pọ le dinku lawujọ. Bakan naa lo rọ wọn pe ki wọn maa gba awọn ọmọ wọn laaye lati maa ba wọn sọrọ nigbakuugba tawọn ọmọ ọhun ba ni iṣoro, ki wọn si maa pariwo sita ti wọn ba kẹẹfin ẹsun ifipabanilopọ lagbegbe wọn.