Gbenga Amos, Ogun
Ẹni ogun ọdun pere ni Idowu Poso, ẹni ọdun mọkanlelogun si lọrẹ ẹ, Friday Abinya Odeh, ṣugbọn akolo awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ lawọn mejeeji wa bayii, nibi ti wọn ti n ka boroboro nipa iwa ọdaju ti wọn hu. Niṣe ni wọn ki baba agbalagba ẹni ogoji ọdun kan, Abdullahi Azeez mọlẹ, wọn ga a lọrun, wọn si pa a, lẹyin eyi ni wọn kun ẹran ara rẹ si wẹwẹ bii ẹran namọ, wọn si yọ apa ti wọn nilo lati fi ṣogun owo.
Gẹgẹ bii alaye ti Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, SP Abimbọla Oyeyẹmi ṣe nipa iṣẹlẹ yii lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹsan-an, oṣu Kẹwaa yii, o ni ilu kan ti wọn n pe ni Kọbapẹ, lẹgbẹ Ṣiun, lọna marosẹ Abẹokuta si Interchange Ṣagamu, ni Abdullahi ti wọn da ẹmi ẹ legbodo naa n gbe.
Ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹfa, ọdun yii, ni oloogbe naa jade nile, wọn lo kan bọ sẹyinkule bii ẹni fẹẹ nasẹ jade ni, afi bo ṣe di pe ko pada wale mọ tilẹ ọjọ naa fi ṣu, o si ṣe bẹẹ dẹni awati.
Lọjọ keji, iyẹn ọjọ kẹsan-an, oṣu Kẹfa ọhun lawọn mọlẹbi baba agba yii lọọ fọrọ ọhun to awọn ọlọpaa leti ni ẹka ileeṣẹ ọlọpaa Owode Ẹgba, pe awọn n wa ẹni wọn, awọn o si mọ ohun to ṣẹlẹ si i.
Nigba tọrọ yii detiigbọ Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, CP Lanre Bankọle, o paṣẹ fawọn ọtẹlẹmuyẹ ni ẹka CID ti wọn n ri si iwa ijinigbe pe ki wọn lọọ ṣewadii iṣẹlẹ naa. Loju-ẹsẹ si ni SP Taiwo Ọpadiran atawọn ọmọọṣẹ rẹ ti fọn saduugbo naa, bi wọn ṣe n fimu finlẹ, ni wọn n ṣewadii, wọn si n wa gbogbo kọlọfin ti oloogbe naa n jẹ si kiri.
Ṣe bawọn kan ṣe mọ nnkan an fi pamọ, bẹẹ lawọn mi-in mọ nnkan an wa dori okodoro, lẹyin oṣu mẹta, lọjọ kejilelogun, oṣu Kẹsan-an to kọja yii, iwadii ijinlẹ tu aṣiri ibuba kan tawọn amookunṣika naa fori pamọ si, Friday Abinya Odeh si lọwọ kọkọ tẹ. Akata ẹ ni wọn ti ri ike siimu Airtel to jẹ ti oloogbe naa.
Friday yii lo ṣamọna awọn ọlọpaa sibi ti ekeji ẹ wa, ko si pẹ rara ti wọn fi ri Idowu naa mu.
Nigba ti wọn de tọlọpaa, awọn mejeeji jẹwọ pe awọn lawọn ji baba agbalagba naa gbe ni nnkan bii aago meje aabọ alẹ ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹfa, to dawati ọhun, wọn ni niṣe lawọn fipa wọ ọ lọ sinu igbo, ibẹ lawọn pa a si, awọn si kun ẹran ara ẹ si wẹwẹ. Wọn ni oogun owo lawọn fẹẹ ṣe, ẹnikan ti wọn pe ni Arab Money, ti wọn lawọn ba pade lori fesibuuku lo sọ awọn ẹya ara eeyan tawọn nilo lati fi ṣoogun owo tawọn ọmọ ‘Yahoo’ maa n ṣe. Etutu to ni kawọn ṣe ọhun lo mu kawọn huwa buruku yii.
Oyeyẹmi ni gbogbo igbiyanju awọn ọlọpaa lati ri ageku oloogbe yii lo ja si pabo, awọn afurasi naa jẹwọ pe awọn ko sin in lẹyin tawọn yọ ẹya ara tawọn nilo tan, niṣe lawọn fọn iyooku rẹ da sigbo kaakiri.
Ṣa, Kọmiṣanna ọlọpaa ti paṣẹ pe kawọn ọtẹlẹmuyẹ tubọ pari iwadii wọn, ki wọn le tete taari awọn ọdaju apaayan yii siwaju adajọ lati lọọ fimu kata ofin.