Idowu ji ọga rẹ gbe, lo ba yin in lọrun pa

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Awọn ẹbi oniṣowo kan, Ọmọlolu Olowoṣọyọ ti kọwe ifẹhonu han si ọfiisi ọga ọlọpaa ti Ẹkun kẹtadinlogun, eyi ti olu-ileeṣẹ wọn wa lagbegbe Fiwaṣaye, niluu Akurẹ, ipinlẹ Ondo, lori ọwọ yẹpẹrẹ ti wọn lawọn agbofinro fi mu ọrọ iwadii iku ọkunrin naa.

Ọkunrin oniṣowo ọhun ni wọn ni dẹrẹba rẹ, Idowu Adekanye, atawọn ẹmẹwa rẹ kan ji gbe, ti wọn si tun pa a ni nnkan bii aago mẹwaa alẹ, ọjọ kẹrinla, oṣu Ki-in-ni, ọdun yii, loju ọna marosẹ Ọrẹ si Ode-Irele, nipinlẹ naa.

Ohun ta a gbọ ni pe ọwọ awọn ọlọpaa pada tẹ Idowu, ṣugbọn awọn ẹlẹgbẹ rẹ yooku raaye sa lọ ni tiwọn.

Wọn gbe afurasi ọdaran yii lọ sile-ẹjọ Majisireeti to wa lagbegbe NEPA, niluu Akurẹ, lẹyin ọpọlọpọ iwadii, nibi ti wọn ti fẹsun mẹrin ọtọọtọ kan an.

Lara awọn ẹsun ti wọn fi kan afurasi ọdaran ọhun ni: didi ọtẹ papọ lati huwa to lodi sofin, ijinigbe ati ipaniyan.

Lasiko igbẹjọ ọhun ni ọlọpaa agbefọba, Taiwo Oniyẹrẹ, fidi rẹ mulẹ nile-ẹjọ pe ilu Oṣogbo, nipinlẹ Ọṣun, ni oloogbe ati Idowu ti n bọ lọjọ naa ki afurasi ọhun too ji i gbe lọ sibi kan nibi ti oun atawọn ẹlẹgbẹ rẹ tawọn ọlọpaa ṣi n wa ti suru bo o, ti wọn si ran an lọrun apapandodo. O ni igi ni wọn kọkọ la mọ oloogbe naa lori, ki wọn too tun yin in lọrun pa.

Oniyẹrẹ ni iwa ti Idowu hu lodi patapata labẹ abala kẹfa ati ikeji ninu iwe ofin Naijiria, ti ọdun 2010, eyi to ta ko ijinigbe. Bakan naa lo tun ni iwa naa ta ko abala okoolelọọọdunrun din mẹrin (316) ninu iwe ofin ipinlẹ Ondo ti ọdun 2006.

Lẹyin eyi ni agbẹnusọ fun ijọba ọhun bẹbẹ niwaju ile-ẹjọ pe ki wọn fi olujẹjọ naa pamọ sinu ọgba ẹwọn Olokuta titi di igba ti wọn yoo fi ri imọran gba lati ọfiisi ajọ to n gba adajọ nimọran.

Kiakia ni agbejọro olujẹjọ, Amofin D. O. Akinbọ, ti ta ko aba naa lori awijare pe agbefọba kuna lati tẹle ofin lori ọna ati asiko to ṣẹṣẹ n fun onibaara oun ni àkọsílẹ̀ iwe ẹbẹ to fi siwaju ile-ẹjọ.

Airi ojutuu ọrọ naa lo mu kí Onidaajọ R. O. Yakubu sun igbẹjọ si ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ ta a wa yii.

Iṣẹlẹ yii lo bi awọn ẹbi oloogbe ọhun ninu ti wọn fi pinnu lati kọwe ẹhonu si igbakeji ọga ọlọpaa Ẹkun kẹtadinlogun, ti wọn si n rawọ ẹbẹ pe ki wọn gba iwadii ọrọ naa kuro lọwọ awọn ọlọpaa teṣan Ode-Irele.

Ni ibamu pẹlu ẹbẹ tawọn ẹbi oloogbe ọhun fi siwaju igbakeji ọga ọlọpaa patapata naa nipasẹ iwe ti agbejọro wọn, Amofin A. K. Akinbuluma, kọ ni wọn ti lawọn ko nigbagbọ mọ ninu iwadii tawọn ọlọpaa Ode-Irele n ṣe.

Wọn ni ominu n kọ awọn lori bi awọn ọlọpaa ṣe kọ lati fi pampẹ ofin gbe awọn ẹlẹgbẹ Idowu ti wọn jọ ṣiṣẹ ibi naa pẹlu bi awọn ṣe n ri awọn afurasi wọnyi ti wọn n yan kaakiri igboro, ti awọn ẹbi Idowu to wa ni ahamọ pẹlu si ti n paara teṣan lori ọna lati gba beeli rẹ.

Wọn ni ọhun ti awọn n fẹ ni ki wọn tẹwọ gba iwadii ọrọ naa funra wọn, nitori awọn ko nigbagbọ ninu iwadii ti awọn ọlọpaa Irele n ṣe mọ.

Leave a Reply