Igbakeji aarẹ tẹlẹ, Ọṣinbajo, gba Tinubu nimọran lori bi nnkan ṣe ri ni Naijiria

Adewale Adeoye

Igbakeji aarẹ orileede yii tẹlẹ, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo, ti rọ ijọba orileede yii pe ki wọn tete wa wọrọkọ fi ṣada lori bi nnkan ṣe le koko lasiko yii, to fi jẹ pe agbara kaka lọpọ araalu fi n rọwọ ki bọ’nu. O waa rọ olori orileede yii, Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu atawọn alabaaṣiṣẹ-pọ rẹ gbogbo pe ki wọn jokoo birikoto, ki wọn wa nnkan ṣe sọrọ naa, nitori pe ohun to n ṣẹle yii kọja afẹnusọ.

Aipẹ yii ni Ọṣinbajo sọrọ naa di mimọ nibi eto pataki kan ti wọn fiwe pe si l’Abuja.

Gẹgẹ bo se wi, ‘‘Ijọba orileede yii gbọdọ tete wa ojutuu si ohun aburu to n ṣẹlẹ laarin ilu bayii. Agbara kaka lọpọ araalu fi n rọwọ ki bọ’nu lasiko yii. O yẹ kijọba pese awọn ohun amayedẹrun kọọkan fawọn araalu bii eto ilera ọfẹ atawọn eto pataki mi-in, nitori pe nnkan ko rọgbọ fawọn araalu lasiko yii. Owo mọto lati lọ sibi iṣẹ kọja afẹnusọ, bẹẹ ni ounjẹ tawọn araalu n jẹ ko ṣee kọ lu mọ.

Ijọba apapọ gbọdọ wa ojutuu sọrọ naa, ki ounjẹ si wa fun kaluku wa. Bi ebi ba tan ninu iṣẹ, iṣẹ buṣe ni. Awọn ọmọde lọrọ naa kan ju lọ, awọn obi wọn ko le fun wọn lounjẹ ẹẹmẹta lojumọ mọ, bẹẹ lawọn ọmọde ko lanfaani lati lọ sileewe mọ lawọn Oke Ọya lọhun-un. Iṣẹ pọ gidi lọwọ ijọba orileede yii lati ṣe, ṣugbọn ju gbogbo rẹ lọ, kijọba wa nnkan ṣe sọrọ ebi to gbalu kan lasiko yii.

Leave a Reply