Igbakeji gomina Ọyọ darapọ mọ ẹgbẹ APC

Ọlawale Ajao, Ibadan

Igbakeji gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Raufu Ọlaniyan, ti fi ẹgbẹ oṣelu PDP silẹ, o ti darapọ mọ APC bayii nipinlẹ Ọyọ.
Ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, lo sọ ọrọ naa di mimọ fawọn akọroyin.
O ni igbesẹ yii waye lori bi awọn alatilẹyin oun ṣe n pariwo pe ki oun kuro ninu ẹgbẹ naa pẹlu bi oun ṣe wa nibẹ lasan ti oun ko ṣe nnkan kan.
O fi kun un pe igbesẹ ti oun gbe yii ko ba ajọṣepọ to wa laarin oun ati Gomina Ṣeyi Makinde jẹ.
O ti to ọjọ mẹta ti awọn eeyan ti n gbe e pooyi ẹnu pe ọkunrin naa fẹẹ kuro ninu ẹgbẹ PDP. Oun paapaa si fẹnu ara rẹ sọ pe ẹgbẹ oṣelu bii marun-un lo n wawọ si oun pe ki oun waa darapọ mọ wọn, ṣugbọn oun ko ti i da wọn loun.
Laipẹ yii ni Makinde kede Bayọ Lawal gẹgẹ bii ẹni ti yoo jẹ igbakeji rẹ lasiko eto idibo ọdun to n bọ, eyi to fi han pe aarin oun ati igbakeji rẹ ti daru.

Leave a Reply