Igbakeji gomina Ọyọ pe awọn aṣofin lẹjọ

Ọlawale Ajao, Ibadan
O ṣee ki igbesẹ ti awọn aṣofin ipinlẹ Ọyọ n gbe lati yọ Igbakeji gomina ipinlẹ naa, Ẹnjinnia Rauf Ọlaniyan, nipo fori ṣanpọn pẹlu bi baba naa ṣe gbe igbimọ awọn aṣofin ọhun lọ si kootu, ọ ni ki adajọ pa wọn laṣẹ lati jawọ ninu igbesẹ naa ni kiakia.
L’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹfa, ọdun 2022 yii, ni igbẹjọ naa yoo bẹrẹ nile-ẹjọ giga to wa laduugbo Ring Road, n’Ibadan, Nitori lati ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, l’Ẹnjinnia Ọlaniyan ti gba kootu lọ, ti ile-ẹjọ si ti jẹ ki awọn alaṣẹ ileegbimọ naa mọ pe ẹjọ wa fun wọn lati jẹ.

Ta o ba gbagbe, lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ karun-un, oṣu Kẹfa, ọdun 2022 yii, lọkunrin ọmọ bibi ilu Igboho, nipinlẹ Ọyọ, yii kede pe oun ko ṣe ẹgbẹ oṣelu People’s Democratic Party (PDP) to gbe oun wọle sipo igbakeji gomina mọ, ẹgbẹ oṣelu All Progresives Congress, APC loun n ṣe bayii.
Pẹlu bo ṣe jẹ pe awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP lo pọ ju lọ nileegbimọ aṣofin ipinlẹ Ọyọ, lọjọ kẹta ti igbakeji gomina kede igbesẹ rẹ naa lawọn aṣofin to jẹ ti ẹgbẹ oṣelu aAlaburada ti pinnu pe yiyọ lawọn yoo yọ baba naa nipo.
Gbogbo ẹṣẹ ti awọn ọnarebu gba pe Ẹnjinnia Ọlaniyan ṣẹ ni wọn kọ sinu iwe ẹsun ranṣẹ si i, wọn ni ko waa ṣalaye idi ti awọn ko ṣe ni i yọ ọ nipo niwaju awọn. Ṣugbọn nigba ti baba naa yoo maa fun wọn lesi, agbẹjọro rẹ lo gbe iṣẹ naa fun, lọjọ kẹrin ti iwe tẹ onibaara rẹ lọwọ loun naa kọwe si wọn pẹlu igboya, o ni ki wọn ma wulẹ dun mọhurumọhuru mọ onibaara oun, bi ọrọ naa ba da wọn loju, ki wọn niṣo ni kootu ki awọn jọ lọọ yanju ẹ nile-ẹjọ.

Igbakeji gomina ti mu ileri ẹ ṣẹ, o ti gbe awọn aṣofin yii lọ si kootu, Ọjọruu gan-an si nigbẹjọ ọhun bẹrẹ ni pẹrẹu.

Leave a Reply