Adewale Adeoye
Ile-ẹjọ to n gbọ ẹjọ ẹsun to jẹ yọ lakooko eto idibo aarẹ nilẹ yii ‘Presidential Election Petition Court’ (PEPC), to wa niluu Abuja, ti bẹrẹ igbẹjọ ẹsun ti awọn ẹgbẹ oṣelu lọlọ-kan-o-jọkan gbe siwaju wọn nipa eto ibo aarẹ to waye lọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Keji, ọdun 2023.
Alaga kootu ọhun to kọkọ sọrọ lọjọ naa, Adajọ Haruna Simon Tsammani, gba awọn lọọya awọn olupẹjọ naa nimọran pe ki wọn ṣohun gbogbo nilana to ba ofin mu, ki wọn si jawọ ninu ohun to le mu ki igbẹjọ ọhun gun ju bo ti ṣe yẹ lọ. Paapaa ju lọ, nigba to ti foju han kedere pe akoko ko si mọ lati fi falẹ rara.
O waa fi da gbogbo awọn agba lọọya (SAN), ti wọn wa nile-ẹjọ ọhun loju pe awọn adajọ ọhun ko ni i ṣegbe lẹyin ẹgbẹ tabi oloṣelu kankan, pe ohun ti ofin ba sọ gan-an lawọn maa tẹle bi ẹjọ naa ba ti bẹrẹ ni pẹrẹu.
O kere tan, awọn agba lọọya (SAN), to le ni igba (200 SAN) ni wọn peju-pẹsẹ sile-ẹjọ ọhun lọsẹ yii.
Oloye Wole Ọlanipẹkun (SAN), lo ṣaaju ikọ awọn agbẹjọro to n ṣegbe fun Tinubu nile-ẹjo naa, Oloye Chris Uche (SAN) lo ṣaaju ikọ awọn agbẹjọro to n ṣoju Alaaji Atiku, wọn si ṣeleri pe awọn yoo ṣohun gbogbo nilana to ba ofin mu.
Wọn ko ti i bẹrẹ igbẹjọ ọhun rara ti gomina ipinlẹ Plateau, Ọgbẹni Simon Lalong ati ondije dupo aarẹ ilẹ yii lẹgbẹ LP, Ogbẹni Peter Obi, Sẹnetọ Victor Umeh, ati alaga ẹgbẹ LP, Julius Abure, fi de sile-ẹjọ naa.
Bẹẹ o ba gbagbe, koko ẹjo ti Alhaji Atiku pe ni pe eru wa ninu awọn esi idibo ti ajọ eleto idibo kede rẹ. O waa rọ ile-ẹjọ pe ki wọn wọgi le gbogbo esi ibo naa, ki wọn si paṣẹ pe ki ajọ INEC tun omiiran ṣe ni kia.
Nigba ti Obi n rọ ile-ẹjọ naa pe oun gan-an ni ki ajọ INEC kede pe lo wọle, niwọn igba ti Tinubu ko ti ri ojulowo ibo ti ofin sọ mu lorigun mẹrẹẹrin orileede yii, paapaa ju lọ niluu Abuja, ti i ṣe olu ilu wa.