Igbẹjọ bẹrẹ lori ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun ti Oludasilẹ ijọ Sọtitobirẹ, Wolii Babatunde, pe

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

 

Ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ ta a wa yii, ni igbẹjọ bẹrẹ lori ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun ti oludasilẹ ijọ Sọtitobirẹ, Wolii Alfa Samuel Babatunde, pe ta ko idajọ ẹwọn gbere tile-ẹjọ giga to wa l’Akurẹ da fun un lori ọrọ ọmọ ọdun kan to deedee sọnu ninu ṣọọṣi rẹ lọjọ kẹwaa, oṣu kọkanla, ọdun 2019.

ALAROYE fidi rẹ mulẹ pe awọn agbẹjọro meje, ti meji ninu wọn jẹ amofin agba, ni wọn ti gbaradi lati gbẹnusọ fun wolii ọhun atawọn osiṣẹ ijọ rẹ marun-un tile-ẹjọ da lẹbi pe wọn gbimọ pọ ji ọmọ to sọnu naa gbe.

Awọn agbẹjọro olupẹjọ rọ kootu ọhun lati fagi le idajọ ẹwọn gbere ti Onidaajọ Oluṣẹgun Oduṣọla da fun onibaara wọn pẹlu awọn ẹri bii mẹtadinlogun ti wọn fi siwaju ile-ẹjọ naa.

Leave a Reply