Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Owolabi Adeekọ ati iya rẹ, Bọla Adeekọ, pẹlu Pasitọ Ṣẹgun Philip ti wọn fẹsun kan pe wọn pa Favour Daley-Ọladele, akẹkọọ-binrin ileewe Lagos State University lọdun to kọja fara han nile-ẹjọ giga ipinlẹ Ọṣun lọjọ Ẹti, Furaidee, opin ọsẹ yii.
Oṣu kejila, ọdun to kọja, ni Owolabi tan Favour, ọrẹbinrin rẹ, lọ sọdọ Pasitọ Philip niluu Ikoyi, nipinlẹ Ọṣun, nibi ti wọn ti pa a, ti wọn si fi ẹya ara rẹ se asejẹ fun Owolabi ati iya rẹ, Bọla.
Ile-ẹjọ Majisreeti ilu Apomu lawọn mẹtẹẹta ti kọkọ fara han lọjọ kẹwaa, oṣu kin-in-ni, ọdun yii, niwaju Onidaajọ Olukunle Idowu-Faith, lọjọ naa si ni adajọ sọ pe ki awọn ọlọpaa lọọ fi awọn olujẹjọ pamọ sọgba ẹwọn ilu Ileṣa.
Olukunle taari ẹjọ wọn sile-ẹjọ giga latari pe Majisreeti ko lagbara lati gbọ ẹsun ipaniyan, o si sun igbẹjọ siwaju di ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu kẹta, ọdun yii, ṣugbọn wahala korona ko jẹ ki igbẹjọ ṣee ṣe nigba naa.
Nigba ti wọn fara han niwaju Onidaajọ Grace Onibokun nile-ẹjọ giga karun-un, niluu Oṣogbo, lọjọ Ẹti, Barisita Kẹmi Bello atawọn agbẹjọro mẹrin mi-in ni wọn ṣoju fun ileeṣẹ to n ri si eto idajọ nipinlẹ Ọṣun.
Nigba ti Adajọ beere pe agbẹjọro awọn olujẹjọ nkọ, ti ko si si ẹnikẹni to dide sọrọ ni lọọya kan to wa ni kootu fi ara rẹ jin lati gbẹjọro fun wọn lọfẹẹ, ṣugbọn Bọla Adeekọ sọ pe awọn gba agbẹjọro, ṣugbọn nigba ti ẹjọ naa ko waye l’Ọjọbọ, Tọsidee, ti adajọ ro pe o maa waye ni ko ṣe fara han loni-in.
Wọn ko ka iwe ẹsun kankan rara nitori pe igba akọkọ ti wọn yoo fara han ni kootu niyẹn, ṣe ladajọ kan sun igbẹjọ siwaju si ọjọ kẹta ati ikẹwaa, ọdun 2021, awọn oṣiṣẹ ọgba ẹwọn si da wọn pada sọgba ẹwọn ilu Ileṣa ti wọn ti wa.