Igbejọ esi idibo aarẹ: Ile-ẹjọ gba ẹri ti Peter Obi ko wa si kootu, wọn lawọn ẹri to peye ni

Faith Adebọla

 Lori igbẹjọ to n lọ lọwọ niluu Abuja, nipa abajade esi idibo aarẹ ti wọn ni Bọla Tinubu ti ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC), lo gbegba oroke, amọ ti Peter Obi fariga pe irọ gbuu ni, Tinubu ko wọle, tọrọ naa si ti da fa-n-fa silẹ ni kootu, olujẹjọ kin-in-ni, ti i ṣe ajọ eleto idibo ilẹ wa, Independent National Electoral Commission (INEC), olujẹjọ keji, Bọla Tinubu, ati olujẹjọ kẹta, APC, ti koro oju si ẹri rẹpẹtẹ kan bayii ti olupẹjọ, iyẹn Peter Obi, ko kalẹ niwaju ile-ẹjọ, wọn ni ki kootu ma ṣe gba awọn ẹri naa wọle rara. Amọ ile-ẹjọ ni ẹri to peye lawọn ẹri wọnyi, wọn si ti gba a wọle.

Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹfa, ti igbẹjọ tun tẹsiwaju nile-ẹjọ akanṣe kan to n gbọ awuyewuye to su yọ lori eto idibo aarẹ, Presidential Election Petition Court, PEPC, lolu-ilu ilẹ wa lọrọ ọhun ti waye.

Lọtẹ yii, niṣe ni olupẹjọ ko akọsilẹ rẹpẹtẹ to ṣafihan iye kaadi idibo alalopẹ, iyẹn Permanent Voters Card, PVC, ti ajọ INEC pin fawọn oludibo nipinlẹ mejilelọgbọn ninu mẹrindinlogoji to wa lorileede wa kalẹ, gbogbo akọsilẹ naa lo si lontẹ ajọ INEC lara lati fẹri han pe ki i ṣe agbelẹrọ rara, ọdọ ajọ eleto idibo naa ni wọn ti ri i gba, bẹẹ lawọn iwe to wa ni bọndu bọndu ọhun ṣafihan iye kaadi awọn oludibo, iye awọn to dibo, iye ibo ti wọn wọgi le ati bẹẹ bẹẹ lọ lawọn ipinlẹ ọhun.

Ọkan ninu awọn lọọya Obi, Amofin agba Peter Afuba, lo ru ẹru iwe naa wa siwaju igbimọ onidaajọ ti Adajọ Haruna Tsammani ṣe alaga fun, wọn ni akọọlẹ ọhun wa lara ‘ẹri maa- jẹ-mi-niṣo’ onibaara awọn lati fi han pe ojooro, jibiti ati jija ẹtọ ọmọlakeji gba ni ijawe olubori Tinubu ati ikede ti INEC ṣe nipa rẹ, o si rọ ile-ẹjọ naa lati gba awọn ẹri ọhun wọle.

Ṣugbọn ẹbẹ yii ko bara de rara lọdọ awọn olujẹjọ mẹtẹẹta, kia ni lọọya INEC, Ọgbẹni Kẹmi Pinhero, ti dide, to si sọ pe, ‘Oluwa mi, mo ta ko awọn ẹri ti olupẹjọ ko kalẹ wọnyi, ẹ ma gba a wọle rara, tori awọn ẹri naa ko nitumọ, a o maa sọ awọn idi ti ko fi nitumọ nigba ta a ba n ṣakojọ awọn atotonu wa bi ẹjọ yii ṣe n lọ.’

Afi bii ẹni pe awọn olujẹjọ naa ti jọ ṣepade esi ti wọn yoo fọ tẹlẹ, niṣe ni agbẹjọro fun Tinubu ati ti APC naa dide, ti wọn si n ṣe asọtunsọ ẹbẹ ti agbẹjọro INEC gbe siwaju adajọ pe ki wọn da awọn ẹri yii nu.

Amọ, lẹyin tawọn adajọ naa fori kori ranpẹ, wọn ni ẹbẹ awọn olujẹjọ, iyẹn Tinubu, INEC ati APC ko ṣetẹwọgba sawọn. Wọn ni gbogbo ẹri lati awọn ipinlẹ mejilelọgbọn naa, ti wọn sami PCN 1, PCN 2, PCN 3 titi de PCN 32 si lara, lawọn gba wọle, awọn yoo si maa sọ idi tawọn fi pinnu lati gba a wọle lasiko idajọ to ba ya, n lẹnu awọn agbẹjọro olujẹjọ ba ṣe wẹlo.

Bakan naa ni kootu tun gba awọn iwe kan to ṣakọọlẹ bi eto idibo naa ṣe lọwọ kan eru ninu nipinlẹ Edo wọle, wọn si tun gba awọn ẹsibiiti kan to da leri akọọlẹ esi idibo ti INEC fi pamọ sori ikanni IReV lati awọn ijọba ibilẹ kan ni ipinlẹ Eko, Benue, Cross River ati Gombe.

Igbẹjọ ṣi n tẹsiwaju lori ẹsun yii.

Leave a Reply