Monisọla Saka
Primate Elijah Ayọdele ti i ṣe oludasilẹ ati olori ijọ INRI Evangelical Spiritual Church, ti ṣekilọ fawọn adajọ maraarun ti wọn n gbọ ẹjọ, ti wọn yoo si ṣedajọ, lori ẹsun tawọn ẹgbẹ oṣelu alatako atawọn oludije funpo aarẹ wọn, fi kan Aṣiwaju Bọla Tinubu ti i ṣe oludije dupo aarẹ lẹgbẹ oṣelu APC, ati aarẹ tuntun ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan lorilẹ-ede yii, pe ki wọn mọ iru ẹjọ ti wọn yoo da, ko si gbọdọ jẹ eyi ti yoo fa ipinya laarin awọn ọmọ Naijiria.
Ọshọ Oluwatosin ti i ṣe agbẹnusọ pasitọ yii lo fọrọ naa lede ninu atẹjade kan to fi sita. Nibẹ ni Ayọdele ti sọ pe ọwọ awọn adajọ wọnyi ni iṣọkan orilẹ-ede Naijiria wa, ati pe idajọ yoowu ti wọn ba fi eru gbe kalẹ, yoo da ogun ati wahala to lagbara silẹ lorilẹ-ede yii.
O ni ki wọn ma ṣe jẹ ki ẹnikẹni ti wọn gbọn-ọn gbọn-ọn, nitori igbẹyin rẹ ko ni i daa fun ilẹ Naijiria gẹgẹ bii orilẹ-ede. O fi kun ọrọ ẹ pe gbogbo agbaye, atawọn ọdọ to n bọ lẹyin, ni wọn n wo eto igbẹjọ naa, nitori ti magomago kankan ba fẹẹ waye.
Bakan naa lo tun rọ wọn pe ki wọn ma ṣe jẹ ki wọn fi owo ra ọmọluabi wọn, o ni ki wọn ma faaye gba fifi owo ra ẹri ọkan wọn, nitori ti wọn ba ṣe bẹẹ, ko ni i ṣai han ninu idajọ ti wọn ba fẹẹ gbe kalẹ lori esi idibo aarẹ ọhun.
Apa kan atẹjade naa lọ bayii pe, “Ọwọ awọn adajọ wa ni iṣọkan ilẹ Naijiria wa. Ti ilẹ Naijiria yoo ba toro tabi ti ko ni i ri bẹẹ, ọwọ wọn lo wa. Eto igbẹjọ awuyewuye to waye latari eto idibo aarẹ to waye loṣu Keji, ọdun yii, kọja ki wọn kan gbe idajọ kalẹ, ọpọlọpọ nnkan ni eto idajọ yii yoo sọ bi yoo ba ṣe ri, titi kan ajọṣepọ ati iṣọkan orilẹ-ede yii.
“Mo waa fẹẹ ke si awọn adajọ wọnyi lati ṣe ohun to tọ, nitori yoo ṣe anfaani fun ilẹ yii lọpọlọpọ. Gbogbo agbaye atawọn ogo wẹẹrẹ ti wọn n bọ lẹyin ni wọn n wo o, wọn si ti ṣetan lati ṣe ohunkohun ti idajọ naa ko ba jẹ ododo. Awọn adajọ gbọdọ ṣe ojuṣe wọn bo ṣe yẹ lori eto idajọ ọhun niru akoko ẹlẹgẹ bayii.
“Wọn maa fi owo nla lọ wọn, ṣugbọn fun anfaani ara wọn ni, ti wọn ko ba gba a. Ẹ jẹ ki ootọ bori ni gbogbo ọna. Ẹ ma kan jẹ ka da ibẹrubojo ati wahala kan sinu ilu, nipasẹ ṣiṣe idajọ ti ko yẹ. Kawọn adajọ wa fi ibẹru Ọlọrun ṣedajọ ni o”.
Ojiṣẹ Ọlọrun yii tun ke si awọn ileeṣẹ eleto aabo lati wa ni digbi, nitori ko ni i ṣai si wahala lẹyin idajọ.
O ni, “Mo tun fẹẹ ke si awọn oṣiṣẹ eleto aabo lati wa ni imurasilẹ daadaa, nitori dandan ni ki wahala ati ija ṣẹlẹ lẹyin ti wọn ba gbe idajọ kalẹ. Ẹni yoowu to ba jare bọ ni kootu, awọn ẹgbẹ oṣelu yooku yoo fọnmu, eyi yoo si bi wahala nla”.
O loun n ke pe awọn ọlọpaa, awọn ṣọja, atawọn ẹṣọ alaabo yooku, lati gbaradi, lojuna ati le pana rogbodiyan yoowu to ba fẹẹ bẹ silẹ.