Gbenga Amos
Ẹkọ ko ṣọju mimu nibi ijokoo kootu to n gbọ ẹsun to su yọ nibi idibo gomina to waye nipinlẹ Ogun lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ karun-un, oṣu Kẹfa yii, ni Isabo, niluu Abẹokuta. Niṣe lorọ di bo o lọ o yago, nigba tawọn tọọgi kan ti wọn ni wọn n ṣiṣẹ fun ẹgbẹ oṣelu APC ya wọbẹ pẹlu pankẹrẹ, ti wọn si lu awọn ọmọ ẹgbẹ alatako to wa nibẹ lalubami.
Lọjọ Aje, ọsẹ yii ni igbimọ to n gbọ ẹjọ awuyewuye to waye lasiko idibo gomina to waye nipinlẹ naa ni ọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹta, ọdun yii, jokoo lati gbọ awọn ẹsun ti oludije ẹgbẹ PDP, Ladi Adebutu mu wa siwaju wọn lori ibo ọhun.
Lasiko ti igbẹjọ naa n lọ lọwọ ni awọn atilaawi yii ya de, niṣe ni wọn ko pankẹrẹ dani bii ọmọ ẹyin eegun, wọn ko si fi ọrẹ ti wọn mu lọwọ ọhun wọn awọn ọmọ ẹgbẹ alatako to wa nibẹ wo, wọn bẹrẹ si i lu wọn bii igba ti tiṣa ba n lu ọmọleewe rẹ.
Ohun to bi awọn eeyan to wa nibẹ ninu ni bi awọn agbofinro to wa ni agbegbe kootu ọhun ṣe yiju sẹgbẹẹ kan ni asiko tawọn tọọgi naa n lu awọn ọmọ ẹgbẹ alatako. Wọn ko le wọn, bẹẹ ni wọn ko wi knni kan.
Ọpo awọn ọmọ ẹgbẹ PDP to wa nibẹ ni wọn sa asala fun ẹmi wọn pẹlu bi wọn ṣe fi agbegbe kootu naa silẹ.
Tẹ o ba gbagbe, lẹyin ibo gomina to waye ni ọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹta yii, ni ajọ eleto idibo ilẹ wa kede Gomina Dapọ Abiọdun gẹgẹ bii ẹni to gbegba oroke lasiko idibo ọhun, ti wọn si ti fun un niwee ẹri ‘mo yege’.
Eyi lo mu ki Ladimeji Adebutu ti oun naa dije lorukọ ẹgbẹ PDP gba ile-ẹjọ lọ, o ni ki awọn adajọ bawọn foju agba wo o, nitori oun loun bori ibo to waye naa, eru lajọ eleto idibo ṣe ti wọn fi kede Dapọ Abiọdun.
Ibẹrẹ igbẹjọ naa lo fẹẹ waye ni Isabo, niluu Abẹokuta, ti awọn tọọgi fi ya bo awọn ọmọ ẹgbẹ alatako to wa si kootu, ti wọn si fi ẹgba le wọn bii ọmọ kekere.
Ṣugbọn owe Yoruba kan lo ṣọ pe ti asinwin ba n sinwin, o maa n moju ina. Bẹẹ lọrọ ri fawọn tọọgi APC yii, nitori pẹlu gbogbo wahala ti wọn fa naa, wọn ko de ọdọ awọn adajọ to wa nikalẹ lati gbọ ẹjọ naa lati ba wọn fa wahala kankan.