Jọkẹ Amọri
Ninu ọdun tuntun yii, ipinya ni oṣere ilẹ wa kan, Yọmi Alore ti gbogbo eeyan mọ si Yọmi Gold, ati iyawo rẹ, Ameenah Abisọla ti gbogbo eeyan maa n pe ni Meenah, fi bẹrẹ ọdun naa pẹlu bi igbeyawo wọn to ṣẹṣẹ fẹẹ pe ọdun kan ṣe tuka. Funra Yọmi lo kọ ọrọ naa, to si gbe e sori Instagraamu rẹ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹta, oṣu Kin-in-ni, ọdun yii pe oun ati iyawo oun ti pin gaari, onikaluku si ti n lọ lọtọọtọ.
Yọmi Gold kọ ọ pẹlu alaye pe, ‘‘Emi ati Meenah ti pinnu lati maa lọ lọtọọtọ. Mo fẹ ki awọn mọlẹbi wa ati awọn ololufẹ wa gba bi o ṣe ri yii fun wa. Asiko yii ki i ṣe eyi ti a le maa da ẹnikẹni lẹbi. Nigba ti ifẹ ba ti ku ninu ajọṣepọ, ko si ẹnikẹni to le fi tipatipa mu un.
‘‘Mo fẹẹ lo akoko yii lati dupẹ lọwọ gbogbo ẹyin ti ọrọ wa jẹ logun ati gbogbo ẹyin ti ẹ ṣe atilẹyin fun wa.
‘‘Meenah jẹ eeyan daadaa, ki i ṣe iru eeyan bii temi yii lo yẹ ko fẹ. Yoo jẹ aya rere ati ololufẹ daadaa fun ọkunrin mi-in to daa ju iru emi yii lọ. Ki i ṣe pe emi naa pe lai ni abuku kankan, ṣugbọn ma a tubọ ṣiṣẹ lori ara mi lati jẹ eeyan to dara si i. A pinnu lati gbe erongba wa lati kọ ara wa silẹ ki kaluku si maa ba tirẹ lọ yii si ita gbangba nitori a fẹ ki gbogbo eeyan mọ nipa ipinnu ti a ṣe yii’’.
Ọpọ awọn to ka ọrọ ti Yọmi kọ sori ikanni rẹ yii lo n ṣe ni kayeefi, inu awọn kan ko si dun pe igbeyawo to ṣeṣẹ fẹẹ pe ọdun kan yii ti fori sanpọn.
Ninu oṣu Kin-in-ni, ọdun to kọja, ni wọn ṣe igbeyawo bonkẹlẹ, igbeyawo yii ni yoo si jẹ ẹlẹkeji ti Yọmi ṣe, nitori o ti kọkọ fẹ ọmọbinrin kan ti orukọ rẹ n je Victoria Ige fun odidi ọdun mẹẹẹdogun, ti wọn si jọ bi ọmọ meji funra wọn. Ọdun 2019 ni igbeyawo naa daru, to si mu ariwo gidi lọwọ pẹlu awọn ẹsun ọlọkan-o-jọkan ti awọn mejeeji fi n kan ara wọn lori ayelujara.
Ko pẹ sigba naa ni Yọmi fẹ Ameenah yii, ti wọn si ṣegbeyawo. Bonkẹlẹ lo fi igbeyawo naa ṣe, wọn ko pariwo rẹ rara, bẹẹ ni ko kede ibi ti wọn ti ṣe e fẹnikẹni, to si paṣẹ lasiko ti igbeyawo ọhun n lọ pe gbogbo awọn ti wọn wa sibẹ ko gbọdọ gbe kamẹra wọbẹ lati ya fọto bi ayẹyẹ naa ṣe lọ, bo tilẹ jẹ pe gbogbo ohun ti ọn n bo naa lo pada tu sita.
Ninu oṣu Kẹrin ọdun to kọja ni iyawo rẹ bi ọmọ ọkunrin fun un ni orileede Amẹrika.