Ọlawale Ajao, Ibadan
Kootu ibilẹ Ọja’ba to wa laduugbo Mapo, n’Ibadan, ti fopin si igbeyawo ọlọdun mẹrin kan to wa laarin Taiwo Barakat Akinṣọla ati Owolabi Rasak Akonṣoọla. N niyawo ba ni Ọlọrun lo ni igbeyawo ọhun wulẹ maa ṣee ṣe tẹlẹ nitori igbeyawo ku ọjọ mẹrin lawọn obi ọkọ oun ti fẹẹ da aarin oun ati ololufẹ oun ru.
Barakat, olukọ ileewe aladaani, to n gbe agbegbe Apata, n’Ibadan yii, ṣalaye pe ọrọ ti ko to nnkan lo maa n bi ọkọ oun ninu, idi si ree to fi jẹ pe lilu ṣaa lo maa n lu oun ni gbogbo igba.
O ni “Gbogbo igba lo máa n na mí, koda, o ti dẹ tọọgi si awọn obi mi ri.
“Ifẹ rẹ ti yọ lọkan mi pẹlu nina to máa n na mí ni gbogbo igba, ati pe o ti sọ pe oun ko ni i jẹ kí n ri aye gbe nitori gbogbo aafaa ti oun ni loun máa fi ba aye mi jẹ.
O maa n doju ti mi kaakiri ni. Ki i sunle. O lu mi lọjọ kẹfa, oṣù kẹsan-an, ọdun to kọja, o gba ọmọ lọwọ mi, o waa le mi da sita.
“Nigba ti mo lọọ fẹjọ ẹ sun ni wẹẹfia, awọn wẹẹfia ni ko gbe ọmọ waa pade mi lọdọ awọn, ọkọ mi lu mi lọjọ yẹn.
“Oun lo fun mi lowo nigba kan pe ki n fi rẹnti ile, Ọlọrun si ṣe e, ile tuntun ni mo ri, ile ọhun ni mo lọọ fi han ọkọ mi to tun ki mi mọlẹ to bere si i lu mi, o ni ile ti mo gba jinna sibi iṣẹ oun.
O pade mi laduugbo NNPC nigba kan, o lu mi, o ja mi sihoho. Ibi gbogbo lo ti máa n yẹyẹ mi kaakiri.
“Lati ọjọ to ti lu mi jade ninu ile ni kaluku ti n gbe lọtọọtọ. Igba kan wa ti mo ti fi ori ji i, ti mo si ti pinnu lati ba a pari ija ka le tun jọ maa gbe papọ, afi bo ṣe ko awọn tọọgi lọọ ka awọn obi mi mọle, ti oun funra rẹ n fọwọ gba baba mi laya, to n gbe wọn ṣepe pe gbogbo nnkan ti wọn ni máa bajẹ ni. Iyẹn lo jẹ kí n pada ṣeleri pe mi o le fẹ ẹ mọ laelae.
Ọlọrun ti kọ ọ pe emi ati Owolabi maa fẹra gan-an ni. Nigba ti igbeyawo wa ku ọjọ mẹrin, emi pẹlu ẹ, a lọọ ra nnkan inawo lọja Aleṣinloye. Ba a ṣe fẹẹ wọnu ile ni mo n gbọ ti awọn obi rẹ n sọrọ mi ni isọ ibajẹ. Mo ni ki Owolabi duro ko jẹ ka gbọ nnkan ti wọn n sọ ninu ile na. Bo tilẹ pe o ba awọn obi ẹ ja gan-an lọjọ yẹn, gbogbo ohun ti wọn sọ lọjọ yẹn loun naa feti ara ẹ gbọ.”
Owolabi ko kọkọ fara mọ pe kile-ẹjọ tu igbeyawo wọn ka, ọkunrin ẹnjinnia to pera ẹ lolugbe agbegbe Apata, n’Ibadan, yii sọ pe iṣoro kan ṣoṣo ti iyawo oun ni ko ju asọtan ọrọ ati ọrọ asọbajẹ lọ.
O ni, “Loootọ, o jẹ onifarada obinrin nitori o ba mi fara da iya nigba ti mi o ti i ni nnkan kan, ṣugbọn ibinu rẹ ti pọ jù. O lọọ binu ba awọn obi mi lọjọ kan, o bẹrẹ si i naka si wọn nimu.
‘’O loun o le jẹ ki n maa ba oun sun, ki n lọọ maa ṣe e nita. Ki i dana ounjẹ. Bẹẹ ni ko raaye fun itọju ọmọ. Ibi iṣẹ ni ṣáà. Emi ni mo máa n tọju ọmọ.
“Ko sẹni ti ko le gbe ṣepe, o ṣepe fun pasitọ ṣọọṣi rẹ paapaa to jẹ agbalagba ẹni ọgọta (60) ọdun.
“Loootọ ni mo máa n na a. Idi ni pe o jẹ ẹni kan tó máa n fi owo ti wọn ni ni idile wọn yangan, aa máa ni olowo lawọn ni idile awọn, awọn ẹgbọn oun meji lo wa niluu oyinbo, oloṣi ni wa nile tiwa.
“Ohun to waa máa n fa lilu ni pe ki i pẹ rara to fi máa n binu fa aṣọ ya mọ mi lọrun, ti yoo si tun maa gbe mi ṣepe.
“Ẹgbọn rẹ ko tọọgi wa lu mi mọle lọjọ kan ti ara mi ko ya. Emi naa waa pe awọn ọrẹ mi. Oun (Taiwo) ni ko jẹ ki àwọn ọrẹ mi lu ẹgbọn rẹ pẹlu bo ṣe sare ko si wọn laarin pe ẹgbọn oun lẹni ti wọn fẹẹ lu.”
O jọ pe ọrọ lilu lilu yii lo bi Oloye Ọdunade Ademọla ti i ṣe aarẹ awọn adajọ kootu naa ninu pẹlu awọn igbimọ rẹ ti wọn fi fopin sí ibaṣepọ ọlọdun mẹrin to seso ọmọ kan naa.
Wọn paṣẹ pe ki olujẹjọ da ọmọ to da wọn pọ pada fun olupẹjọ, ko si maa san ẹgbẹrun maru-un marun-un naira (N5,000) fun obinrin náà gẹgẹ bii owo itọju ọmọ ọhun loṣooṣu.