Jide Alabi
Bo tile jẹ pe titi si ba a ṣe n sọ yii ni awọn ṣọja ti wọn lọọ kọ lu awọn ọdọ to n ṣewọde SARS ni Lẹkki sọ pe awọn ko yinbọn pa ẹnikẹni lasiko ikọlu naa. Ọrọ beyin yọ nigba ti igbimọ ti ijọba Eko gbe kalẹ lati gbọ ifisun awọn araalu ati iṣẹlẹ Lẹkki ṣabẹwo si ibi ti iṣẹlẹ naa ti waye ni ọjọ Eti, Furaidee, ọse yii, pẹlu bi wọn ṣe ri awọn ajoku ọta ibọn ti wọn yin nibi ṣẹlẹ ọhun. Bii mẹfa ajoku ọta ibọn naa ni awọn eeyan naa ri, eyi to fi han pe loootọ ni awọn ṣọja yinbọn.
Awọn ajoku ọta ibọn ti wọn ri niṣoju awọn oniroyin to tẹle wọn lọ sibẹ ati aṣoju awọn oṣiṣẹ Too-Geeti Lẹkki yii ni igbimọ naa ti alaga wọn, Dorris Okuwobi, ko sodi, yoo ṣiṣẹ le lori lati fidi ododo mulẹ lori iṣẹlẹ ọhun.