Ni bayii, o da bii pe ẹgbẹ awọn Kristẹni ti wọn n pe ni CAN (Christian Association of Nigieria) ẹka ti ilu Ọyọ ti mura lati wọ ṣokoto ija pẹlu Alayeluwa, Iku Baba Yeye, Ọba Lamidi Ọlayiwọla Adeyẹmi Kẹta, Alaafin ilu Ọyọ. Ọrọ ilẹ kan lo fẹẹ da ija wọn silẹ, ọrọ naa si ti ni ti ọlọpaa ninu. Awọn CAN Ọyo yii ni awọn lawọn ni ilẹ kan ni agbegbe Ayetoro niluu naa, ṣugbọn Alaafin ni, aṣiṣe ati aṣisọ gbaa ni, nitori ilẹ ti awọn eeyan naa n wi yii, ilẹ ilu ni, oriade lo ni in.
Iwe iroyin Punch lo ti kọkọ gbe iroyin kan jade pe awọn aṣaaju ẹgbẹ CAN ilu Ọyo fi ehonu wọn han pe ilẹ awọn kan ni Ayetoro to n lọ si bii pulọọti mẹrindinlọgọrun-un (96), iyẹn bii eeka mẹrindinlogun, Alaafin ti fẹẹ ja ilẹ naa gba o, nitori o ti n ta nibẹ, bẹẹ ọwọ ijọba ibilẹ Atiba lawọn ti ra ilẹ awọn. Lanaa ode yii, niluu Ibadan, Biṣọọbu Daniel Oluwajimade, ti i ṣe ọkan ninu awọn ọmọ ẹgbẹ CAN Ọyọ yii ni ọdun kẹrindinlogun (16) sẹyin lawọn ti ra ilẹ yii, ti awọn si n sanwo rẹ fun ijọba Atiba lọdọọdun. O ni lojiji lawọn ri i pe Alaafin ti wọ inu ilẹ naa, to n ta a fun awọn oniṣowo kan, nigba ti awọn si sọrọ, awọn ọlọpaa Atiba ranṣẹ si aṣoju CAN to wa lagbegbe wọn, wọn si ti gbe ọrọ naa lọ si Iyaganku nIbadan. Biṣọọbu naa ni gbogbo ohun ni ti awọn sa fẹ ni ki Alaafin kuro lori ilẹ awọn.
Ọrọ yii lo bi Alaafin ninu, ni Ọba Adeyẹmi ba fitan balẹ. O ni ilẹ ti wọn n wi yii, ki i ṣe Ayetoro bi awọn ti pe e, Gbofin ni ibẹ n jẹ, orukọ atayebaye ni, ọkan ninu awon ilẹ Ọba si ni. Ninu iwe ti Kabiyesi kọ, o ni ki i ṣe eeka mẹrindinlogun lo wa lori ilẹ naa bi awọn CAN Ọyọ ti wi yii, ilẹ to le ni ẹgbẹrun eeka ni. Kabiyesi ni awọn Alaafin ni i maa i fun awọn ọmọọba kọọkan nilẹ nibẹ lati lọọ kọle, tabi ṣe ohun t o bawu wọn, ile to si ti wa nibẹ bayii ti le ni ẹgbẹrun meji. O ni yatọ si eyi, ọdun kẹrindinlọgbọn ree ti oun Alaafin Adeyẹmi funra oun ti ṣe sọfee (survey) ilẹ naa, ti oun wọn ọn, ti awọn si gba aṣẹ onilẹ lọwọ ijọba. Bi awọn kan ba waa lọ lẹyin ti wọn ji ilẹ onilẹ ta fun CAN, ti wọn jọ ṣe magomago laarin ara wọn, njẹ orọ naa ko buru bẹẹ.
Alaafin ni ija ti awọn ẹgbe CAN naa n ja buru, paapaa nigba ti eeyan ba woye pe ẹgbẹ ẹlẹsin ni wọn, ti ko si yẹ keeyan ba wọn nidii ibajẹ tabi jibiti kankan. Ọrọ naa ko ti i yanju, nitori awọn CAN yii n sọ pe ija ṣẹṣẹ bẹrẹ ni, bẹẹ ni awọn ara aafin n sọ po ko si ija nibi kankan, ọrọ ni ko ye awọn araabi naa, bo ba ya yoo ye wọn.