Ko si tabi ṣugbọn kan nibẹ pe ọgbọn oloṣelu ni Oloye Nnamdi Azikiwe fẹẹ lo fun awọn ti wọn n ṣeto idibo, o si fẹẹ fi juujuu bo gbogbo eeyan loju ni. Ofin eto idibo ti la ọrọ naa kalẹ, ohun ti ofin naa si sọ ni pe ki gbogbo eeyan to ba mọ pe oun yoo du ipo aarẹ orilẹ-ede Naijiria ri i pe awọn san owo-ori awọn pe perepere. Wọn ni ki i ṣe pe ki tọhun ṣẹṣẹ lọọ sare san owo-ori ẹ lẹyin ti eto idibo ti bẹrẹ, to jẹ pe tọhun yoo ti mọ pe oun fẹẹ dupo, nitori ẹ lo si ṣe lọọ sanwo ori. Wọn ni ẹnikẹni to ba ṣe eleyii, wọn yoo ka a kun ẹni ti ko sanwo ori ni, nitori ko yẹ ko jẹ nigba ti aṣaaju ba ni nnkan kan lati gba lọwọ araalu tabi ijọba ni yoo maa sare lọọ sawo-ori, ojuṣe to yẹ ki gbogbo aṣaaju maa ṣe ni. Ohun to jẹ ki Azikiwe ni iṣoro niwaju ajọ FEDECO to n ṣeto idibo nigba naa ree, nitori awọn yẹn ni awọn ko ni i gba orukọ ẹ wọle.
Ni ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu kẹrin 1979, Azikiwe ko gbogbo awọn oniroyin jọ. Awọn oniroyin Naijiria lo pọ ju, ṣugbọn awọn aṣoju ileeṣẹ iroyin ilẹ okeere naa wa nibẹ, o ni nitori ọrọ ti oun fẹẹ sọ, ọrọ agbaye ni. Ọrọ agbaye kẹ! Eyi lo jẹ ki awọn oniroyin maa ṣubu lu ara wọn, wọn si jokoo wọọrọ sibi ti Azikiwe pepade si, wọn ni awọn ṣetan lati gbọrọ lẹnu ọmọwe oloṣelu to gboyinbo bii awọn araalu ọba. Ṣugbọn nigba ti Azikiwe de, o ni aaye oyinbo rẹpẹtẹ paapaa ko si, ohun ti oun pe wọn fun ni pe oun waa tun ọmọluabi oun ṣe ni. “Gẹgẹ bi orukọ mi, ati ipo pataki ti mo ti di mu ni Naijiria yii, gẹgẹ bii olori orilẹ-ede yii lẹẹkan ri, mo fẹẹ sọ fun gbogbo ẹyin oniroyin tiẹ duro yii pe irọ buruku ni Oloye Michael Ani ti i ṣe alaga ajọ to n ṣẹto idibo ilẹ wa, FEDECO, pa mọ mi.
“Ẹyin naa ti gbọ ti ọkunrin naa n ke tantan pe Azikiwe ko sanwo-ori, Azikiwe ko sanwo-ori! Ọrọ to n sọ yii ko ri bẹẹ, nitori emi sanwo-ori ni temi o. Mo sanwo-ori mi ni ọdun 1976 si 1977, mo san ti 1977 si 1978, mo si ti san ti 1978 si 1979. Ohun ti ọkunrin olori FEDECO yii wa n sọ ko ye mi, idi ti mo si fi jade si gbangba ree, ko too di pe mọ gba ile-ẹjo lọ, nitori bi wọn ba sọ ọrọ naa ti ko tẹ mi lọrun, ile-ẹjọ ni yoo ba wa yanju ẹ. Ẹgbẹrun mẹta Naira o le (N3,062.75) ni owo ti mo san lọdun 1976 si 1977 yẹn o, o kan jẹ pe ninu awọn ipin idokoowo ti mo ni ni wọn ti yọ owo naa ni. Ohun ti ko ye Ani naa ree, kaka ko si pe mi jokoo ki n ṣalaye ọrọ fun un, o sare gbe atẹjade sita pe Azikiwe ko sanwo-ori. Nibo ni wọn ti n ṣe iru iyẹn, bawo ni yoo ṣe ṣe iyẹn fun mi laarin gbogbo awa ti a jọ fẹẹ du ipo aarẹ!”
Ṣugbọn ọrọ ti Azikiwe sọ pẹlu awọn oniroyin yii tubọ bi Michael Ani ninu ni, n loun naa ba jade, o loun ko laiki bi Azikiwe ti sọrọ laali oun ni gbangba, oun ko fẹ iru ọrọ bẹẹ rara, nitori agbalagba ni Azikiwe, ko si yẹ ki wọn ba a nibi ti yoo ti maa jo langbalangba kikri. Oun naa ba awọn oniroyin Daily Times sọrọ lọjọ kan naa ti Azikiwe sọ ọrọ tirẹ, ohun to si wi ni pe ko si ihalẹ ti eeyan yoo ṣe fun onigẹgẹ ti yoo pọ ti ọfun rẹ silẹ o, ohun ti oun sọ nipa Azikiwe, ododo ọrọ gbaa ni. Baba yii ko sanwo-ori, o kan fẹẹ fi ṣakara pe oniroyin ati oloṣelu loun bo nnkan mọlẹ ni. “Ẹ wo o, ọrọ ti mo n sọ yii, emi mọ ohun ti mo n wi o!”, Michael Ani lo n sọrọ yẹn o, ọga awọn FEDECO. “Ṣe ẹ ri i, Ki ọrọ too di gbangba bayii, Oloye Azikiwe ti kọwe si mi, to ni ki n fọwọ sowọ pọ pẹlu oun, o ni ki n ṣe oun daadaa, itumọ ohun to si n wi ko ye mi.
“Ṣe ki n fọwọsọwọpọ pẹlu ẹ ki n waa parọ fun awọn araalu ni, abi iru ifọwọsọwọ wo lo n beere lọwọ mi. Ọrọ yii o ruju rara, ki Azikiwe ko risiiti to fi sanwo-ori ẹ wa, risiiti yii naa ṣaa la fi n ṣe akọsilẹ ohun ti a n ṣe. Emi kọ ni mo ni risiiti, emi kọ ni mo n wa a, n ko si mọgba ti Azikiwe gba risiiti ẹ, risiiti to ti ko fun lemi fi n ṣe ohun tijọba ni ka ṣẹ. Ninu risiiti yii naa lo ti han pe Oloye Azikiwe ko sanwo ori ẹ nigba to yẹ ko san an. Ko san owo-ori ọdun 1976 si 1977 lọdun yẹn rara. O san diẹ ninu owo-ori ti 1976 si1977 yii lasiko to n san ninu owo-ori ti 1977 si 1978. Ẹẹmẹta lo sanwo ori 1977 si 1978, bẹẹ ni ki i ṣe ọdun yẹn tabi igba to yẹ ko san an lo san an, o san gbogbo ẹ pọ lasiko to n sanwo-ori 1978 si 1979 ni, iyẹn lẹyin ti awa ti kọwe si wọn lati FEDECO nibi pe ki wọn ko iwe ori wọn jade. Ninu oṣu keji la kọwe si wọn, oṣu kẹta ni Azikiwe sanwo-ori ẹ. Ki waa lo n sọ pe Michael Ani ko mọ ohun to n sọ si!”
Aṣiri buruku ti Ani tu yii ka awọn ẹgbẹ NPP lara gan-an ni, iyẹn awọn ẹgbẹ Azikiwe, ẹgbẹ to ti fa a kalẹ lati dupo aarẹ lorukọ wọn. Ohun to si n dun wọn ni pe ọrọ naa ti n di yẹyẹ laarin awọn ẹgbẹ oṣelu to ku, pe ẹni ti ẹgbẹ NPP fa kalẹ, Azikiwe bo ṣe lagbara to, ko ni iwe ori, bẹẹ lo n kọwe si awọn ti wọn n ṣeto idibo pe ki wọn fọwọ sowọ pọ pẹlu oun. N lawọn naa ba binu, Paul Nnongo ti i ṣe akọwe ẹgbẹ naa si ni ọrọ ti doju ẹ, awọn yoo kuku gbe iwe ti Azikiwe kọ si Michael Ani jade, ko fi le mọ pe ko si awo kan ninu awo ẹwa, ko si igba kan ti Azikiwe beere awọn ohun ti ko ṣee ṣe tabi ti ko dara lọwọ ‘Ani. Ni Nnongo ba gbe iwe naa jade, ohun ti Azikiwe si kọ sibẹ ni pe awọn akauntanti oun, iyẹn awon aṣiro-owo to wa nidii eto owo-ori oun ṣe awọn aṣiṣe kan, ati pe ko si alaga ẹgbẹ awọn nile, nitori ẹ lo ṣe jẹ oun funra oun loun kọwe si Ani. O si ki i pe o ṣeun bo ṣe n fọwọsowọpọ pẹlu oun.
Ṣugbọn pẹlu gbogbo eleyii naa, ohun ti Ani ṣaa n wi ni pe Azikiwe ko san owo-ori, bẹẹ ni Azikiwe n pariwo kiri pe oun san owo-ori. Nigba tọrọ naa fẹẹ burẹkẹ, ẹni kan to jẹ agbalagba ninu ẹgbẹ NPP, ẹni to mọ bi Azikiwe ṣe denu ẹgbẹ naa, to si di oludije ipo aarẹ lorukọ ẹgbẹ wọn, iyẹn Oloye Adeniran Ogunsanya, ko agbada rẹ kọrun nijọ kan, iyẹn lọjọ kẹta, oṣu karun-un, ọdun 1979, o gba ileeṣẹ awọn FEDECO lọ, ni Sẹkiteeria ijọba l’Ekoo. Ogunsanya ko wa ẹni meji lọ, Michael Ani lo tori ẹ lọ, ohun to si ba lọ naa ni bi ọrọ to wa nilẹ naa ko ṣe ni i dele-ẹjọ, o ni ki ọkunrin olori awọn FEDECO naa wo nnkan ṣe fun Azikiwe, ko si ma ṣẹ jẹ ki ọrọ ti awọn mejeeji ba n fa di ohun tawọn oniroyin yoo maa gbe kiri, nitori bi ọwọ awọn oniroyin ba ti tẹ ọrọ kan, wọn yoo fọ ọ bii aṣọ titi ti yoo fi gbo ni.
Ṣugbọn pẹlu abẹwo yii naa, Ani ni oun ko ti i mọ bi oun ṣe le ran Azikiwe ati ẹgbẹ oṣelu rẹ lọwọ, nitori ofin ti sọ pe ẹni ti ko ba sanwo-ori ko le du ipo aarẹ, bẹẹ lofin sọ pe ẹni ti ko ba san owo naa ni asiko to yẹ ko san an, ki wọn ka a si ẹni ti ko sanwo-ori ni. Ki waa ni toun ninu ọrọ yii. Oun ko ṣaa ni i yi ofin pada nitori oludije kan ṣoṣo, pe ohun kan naa to le mu nnkan rọgbọ fun Azikiwe ni ko wa iwe to fi sanwo ori ni 1976 si 1977 jade. Azikiwe mọ pe nnkan fẹẹ daru ree, nitori awọn kan ti n kun hunrunhunrun ninu ẹgbẹ NPP pe ti awọn FEDECO ba lọọ ja a bọ silẹ, yoo pẹ fun ẹgbẹ awọn ki awọn too le ri ẹlomi-in gbe dide o. Wọn ni ki wọn tete yọ Azikiwe ki wọn fi ẹlomi-in rọpo ẹ, ko too di pe yoo ba ọrukọ ẹgbẹ awọn jẹ. Azikiwe mọ pe ipo aarẹ fẹẹ bọ ree, ati pe bi oun ko ba tete, orukọ oun yoo tun bajẹ pẹlu ẹ ni.
Nidii eyi, bi iṣẹ ko pẹ ni, ẹni kan ki i pẹṣe. Azikiwe bẹ lọọya rẹ lọwẹ, o ni ko niṣo nile-ẹjọ. Ni wọn ba sare pe ẹjọ o, wọn ni FEDECO fẹẹ fiya jẹ Azikiwe, wọn ko fẹ ko du ipo aarẹ lorilẹ-ede baba rẹ, wọn fẹẹ fọwọ ọla gba a loju.