Ija orogun: Maryam fọmọ-odo fọ iyaale rẹ lori, niyẹn ba ku patapata

Abilekọ kan, Maryam Ibrahim, yoo rojọ, ẹu rẹ yoo fẹrẹ bo ko too le bọ ninu ajaga to ko ara rẹ si yii, iyẹn ti ẹṣẹ to ṣẹ ọhun ko ba la ijiya iku lọ fun un. Iyaale rẹ, Hafsat Ibrahim, lo lọọ ba ninu yara ti iyẹn wa, to si la ọmọ-odo mọ ọn lori, tiyẹn si gbabẹ ku ni ipinlẹ Bauchi.

Gẹgẹ bi atẹjade ti Alukoro ọlọpaa ipinlẹ naa, Ahmed Mohammed Wakil, naa fi sita faọn oniroyin nipa iṣẹlẹ yii, ṣalaye pe Maryam to n gbe ni abue kan ti wọn n pe ni Gar, ni Wọọdu Pali, nijọba ibilẹ Alkaleri, nipinlẹ naa lọwo awọn tẹ lọjọ kejilelogun, oṣu Kọkanla ọdun yii lori ẹsun pe o pa iyaale rẹ.

Ọkọ awọn obinrin yii, Ibrahim Sambo, ẹni ogoji ọdun lo mu ẹsun iyawo rẹ lo si agọ ọlọpaa kan to wa ni Maina-Maji, ti ọkunrin ẹni ogoji ọdun yii si ṣalaye fun wọn pe Maryam ti la odo mọ iyawo oun keji lori, iyẹn si ti ṣeṣe gidigidi, eyi to mu ki wọn sare gbe e lọ si ileewosan alabọọde to wa ni abule naa.  Ṣugbọn awọn dokita to yẹ obinrin naa wo sọ pe oku ni wọn gbe wa.

Nigba ti awọn agbofinro gbọ pe obinrin naa ti ku, wọn ko fi akoko ṣofo rara ti won fi lọọ gbe iyawo to ṣiṣẹ buruku yii.

Ko si da awọn ọlọpaa laamu rara to fi jẹwọ pe loootọ loun wọnu yara iyaale oun lọ loru, ni nnkan bii aago mejila, ti oun si la ọmọ-odo mọ ọn lori.

Nigba to n ṣalaye idi to fi ṣe bẹẹ, ọmọbinrin yii ni ni nnkan bii aago mọkanla aarọ ọjọ kejilelogun, oṣu Kọkanla, ni iyaale oun yii, Hafsat Ibrahim, ẹni ogun ọdun, ran ọmọ rẹ ọkunrin, Abdulasis Ibrahim, ẹni ọdun marun-un, pe ko waa fun oun ni idi ẹran dindin ti wọn n pe ni (Tsire) lede wọn. O ni b’oun ṣe jẹ ẹran naa tan ni ara oun ko lelẹ mọ, ti inu bẹrẹ si i run oun. Nibi tọrọ naa le de, niṣe ni oun bẹrẹ si i bi.

O ni akiyesi toun ṣe yii loun fi pe iyawo aburo ọkọ awọn kan torukọ rẹ n jẹ Faiza Hamisu, toun si fọrọ naa to o leti.  O ni obinrin yii sọ foun pe o ṣee ṣe ko jẹ pe ọgbẹ inu lo n yọ oun lẹnu.

Ṣugbọn o jọ pe idahun ti iyawo aburo ọkọ Maryam fun un ko tẹ ẹ lọrun. O si jọ pe o fura si iyaale rẹ. Pẹlu ibinu ni Maryam fi wọn ile iana wọn lọ, to si lọọ gbe ọmọ-odo nibẹ.  Bo ṣẹ gbe e, yara iyaale rẹ lo mori le, to si fi ọmọ-odo naa fọ ọ lori.

A gbọ pe obinrin naa ṣeṣẹ gidigidi, eyi to mu ki wọn gbe e lọ si ileewosan alabọọde kan, ṣugbọn ibẹ ni awọn dokita ti fidi rẹ mulẹ pe obinrin naa ti ku.

Titi di ba a ṣe n sọ yii la gbọ pe obinrin naa wa lọdọ awọn ọlọpaa, nibi to ti n ran wọn lọwọ lori iwadii wọn.

 

Leave a Reply