Pẹlu ohun to ṣẹlẹ nibi eto idibo awọn oloye ẹgbẹ oṣelu PDP nilẹ Yoruba, eyi to waye ni Wocdiff Centre, niluu Osogbo, lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, o jọ pe ija ajaku akata to ti n fojoojumọ ṣẹlẹ laarin Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, ati gomina ipinlẹ Ekiti tẹlẹ, Ayọdele Fayoṣe, ti rodo lọọ mumi.
Ẹyi ko sẹyin bi Fayọsẹ ṣe tọrọ aforiji lọwọ Gomina Makinde, to si ni oun gba a gẹgẹ bii ọga oun ninu ẹgbẹ oṣelu PDP nilẹ Yoruba.
Niṣe ni Oṣokomole gẹgẹ bi wọn ṣe maa n pe Fayoṣe so mọ Makinde, to si sọ ni gbangba nigba to n sọrọ pe ‘’Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ṣeyi Makinde, ọrẹ mi, arakunrin mi ati aṣaaju mi nipa oore-ọfẹ Olọrun.
‘’Ṣeyi Makinde ni aṣaaju wa, oun naa ni yoo si maa ṣe aṣaaju wa, ọta ko le raaye wọ aarin wa nitori ọkan naa ni wa. Sababi ni awọn wahala to ṣẹlẹ ninu ẹgbẹ oṣelu PDP. Ta ni aṣaaju wa, Ṣeyi Makinde ni aṣaaju wa, Oyinlọla ni aṣaaju wa, Ṣẹgun Oni ni aṣaaju wa. Gbogbo ibi ti esi idibo to n waye lonii ba yọri si ni mo maa fara mọ.
‘’Ti mo ba ti ṣẹ ẹnikẹni ninu ẹgbẹ wa yii, mo tọrọ aforiji, bi ẹnikẹni ba ṣi ṣẹ emi naa paapaa, mo ti dariji iru ẹni bẹẹ. Bo ba jẹ pe Arapaja lo bori ninu idibo naa, mo maa ṣatilẹyin fun un. Mọlẹbi kan naa ni wa, a si gbọdọ ṣe atunto si ẹgbẹ naa ko le wa ni ipo to daa.
‘’Tẹ o ba gbagbe, o ti to ọjọ mẹta ti ija agba ti n lọ laarin Gomina Makinde ati Fayoṣẹ. Ohun ti gomina ipinlẹ Ekiti tẹlẹ naa si n tẹnumọ ni pe oun ni iriri ju Ṣeyi Makinde lọ nidii oṣelu. O ni oun wa ninu awọn ti wọn gbe e wọle, pe o si jẹ gomina ko sọ pe o jẹ ọga oun.
Ṣugbọn awọn mi-in naka aleebu si gomina Ekiti tẹlẹ yii lasiko ija naa, wọn ni ija ẹbi lo n ja nitori nigba ti oun naa wa nipo gomina, to si jẹ oun nikan ni gomina ẹgbẹ PDP lati ilẹ Yoruba, oun ni olori ẹgbẹ wọn, iru ọwọ yii ni wọn reti ki Fayoṣe fun Ṣeyi Makinde to ni oun ko ni i fun un.
Ọrọ naa si le debii pe kobakun-gbe ọrọ ni Oṣokomọle fi maa n ranṣẹ si Makinde ni gbogbo igba. Gbogbo awọn ti wọn si gbero lati pari ija naa ni ko ṣee ṣe fun wọn.
Ṣugbọn ija naa pari lasiko ti wọn n dibo awọn oloye ilẹ Yoruba yii, nibi ti Fayoṣe ti sọ ni gbangba pe oun gba Ṣeyi Makinde gẹgẹ bii ọga ati aṣaaju oun.