Stephen Ajagbe, Ilorin
Adugbo Ifẹsowapọ, lagbegbe Tankẹ, niluu Ilọrin, kan gogo l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, nitori bi ijamba ina ṣe gbẹmi iya atawọn ọmọ rẹ mẹrin.
ALAROYE gbọ pe abẹla ti wọn tan lo fa ijamba ina naa. Nigba ti wọn ni abẹla naa jo tan ti gbogbo wọn si ti sun fọnfọn ni ina bẹrẹ si i jo awọn nnkan to wa nitosi ẹ.
Bo tilẹ jẹ pe awọn panapana lọ sibi iṣẹlẹ naa lati pa ina ọhun, sibẹ, awọn mẹta ti jona ku loju ẹsẹ ninu ina naa.
Iroyin to tẹ akọroyin wa lọwọ laaarọ ọjọ Ẹti (Furaidee), ni pe ọmọ kan ṣoṣo torukọ rẹ n jẹ Abideen, to mori bọ ninu ijamba naa lọjọ iṣẹlẹ ọhun ti pada jade laye nilewosan ẹkọṣẹ Fasiti Ilọrin, UITH, nibi ti wọn gbe e lọ fun itọju.
Alaga adugbo Ifẹsowapọ, Ọgbẹni Yinka Awodun, ni ṣadeede lawọn araadugbo gbọ igbe wọn, ṣe ni wọn n pariwo kikankikan, ṣugbọn nigba tawọn eeyan debẹ, wọn ko le doola wọn ninu ina naa.
Lanlọọdu ile naa, Ọgbẹni Ibrahim Gana, ṣalaye pe baba awọn ọmọ naa ko si nile lasiko tiṣẹlẹ naa ṣẹlẹ.