Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Titi digba ti a n ko iroyin yii jọ, kẹu ni ina ṣi n jo nileeṣẹ kan ti wọn ti n ta nnkan ẹṣọ ile, Art Deco Gallery, to wa loju ọna Alekuwọdo, niluu Oṣogbo.
Gbogbo igbiyanju awọn araadugbo ati awọn oṣiṣẹ panapana lati pa ina naa lo ja si pabo, ṣe ni ina ọhun n fẹju bii ina inu ẹẹrun.
Gẹgẹ bi obinrin kan to n gbe lagbegbe naa, to pe orukọ ara rẹ ni Yetunde ṣe ṣalaye, o ni ni nnkan bii aago meji oru ni ijamba ina naa bẹrẹ, waya ina kan la gbọ pe o ja ninu ṣọọbu kan ti wọn ti n ta timutimu (foam).
Bi ina ṣe bẹrẹ nibẹ lo n ran mọ gbogbo nnkan to wa layiika, ko si pẹ rara to fi ran mọ Art Deco Gallery to jẹ ile alaja meji ọhun.
Yetunde fi kun ọrọ rẹ pe gbogbo awọn ti wọn n gbe inu ile ti wọn ti n ta foomu fọn sita lai mu ohunkohun, bi awọn kan ṣe n bu omi, lawọn kan n pe ileeṣẹ panapana.
Ṣugbọn ijọloju lo jẹ pe bi wọn ṣe n pa ina naa to naa lo tun n pọ si i, ṣe ni eefin n ru lati origun kan si ekeji, titi ti ilẹ fi mọ, ti wọn ko si ri ohunkohun mu jade nibẹ.
Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ naa, ọga agba kan nileeṣẹ Sifu Difẹnsi nipinlẹ Ọṣun, CSC Abioye Toyin, ṣalaye pe aago meji oru ti ina naa bẹrẹ lawọn ti gbọ, ti awọn si ti wa sibẹ.
O ni awọn ba awọn ajọ panapana ti ijọba apapọ nibẹ, awọn si gbiyanju lati pa ina naa. Bo tilẹ jẹ pe ko si ẹni ti ẹmi rẹ ba iṣẹlẹ naa lọ, sibẹ ọkẹ aimọye miliọnu Naira ni dukia to ṣofo nibẹ.