Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ọpọ dukia olowo iyebiye lo ṣegbe sinu ijamba ina kan to waye loru ọjọ Aiku, Sannde, mọju ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ ta a wa yii, niluu Ikarẹ Akoko, nijọba ibilẹ Ariwa Ila-Oorun Akoko.
ALAROYE gbọ lati ẹnu ẹnikan ti iṣẹlẹ naa ṣoju rẹ pe ni nnkan bii aago mẹta oru lawọn deedee ri abami ina ọhun to ṣẹ yọ lati inu ile nla kan to ni ọpọlọpọ ṣọọbu, eyi to wa l’Opopona Jubilee, niluu Ikarẹ.
O ni gbogbo akitiyan awọn araadugbo lati ri ina yii pa lasiko to ṣẹṣẹ n bẹrẹ lo ja si pabo latari titi gbọningbọnin ti awọn geeti atawọn ṣọọbu to wa ninu ile naa wa.
O ni ina naa ti gbilẹ kọja ohun tapa tun le ka mọ lati pa lẹyin tawọn jaja ri geeti ile itaja nla ọhun ja wọle.
Gbajugbaja ṣọrọṣọrọ kan to jẹ ọkan ninu awọn to ni ṣọọbu sinu ileetaja ọhun, Akeem Ọdẹdina, ẹni tọpọ eeyan mọ si Ọmọ Ọdẹ, juwe iṣẹlẹ naa bii ajalu nla fun gbogbo awọn to fara gba.
Ọmọ Ọdẹ ninu ọrọ to b’ALAROYE sọ lori aago ni bo tilẹ jẹ pe oun ko si niluu Ikarẹ lasiko tọrọ ina ta a n sọ yii bẹrẹ ṣugbọn iroyin ti oun gbọ nipa iṣẹlẹ ọhun fihan pe ọrọ naa ki i ṣoju lasan.
O ni titi di asiko yii lohun to le ṣokunfa ijamba ina ọhun ṣi n ṣe awọn eeyan ni kayeefi, nitori pe lati bii ọjọ mẹta sẹyin lawọn eeyan agbegbe Jubilee, n’Ikarẹ Akoko, ti ni ina ijọba kẹyin ṣaaju ọjọ ti ijamba ina ọhun waye.
O ni awọn dukia to le ni miliọnu mẹẹẹdogun Naira loun nikan padanu sinu ina abami ọhun lai sọ ti awọn nnkan mi-in to ṣegbe sinu awọn ṣọọbu yooku.
Ọmọ Ọdẹ ni ohun to jẹ ki ofo ọhun pọ to bẹẹ lọrọ ileeṣẹ panapana to wa niluu Ikarẹ ti ko ṣiṣẹ.
O ni awawi pe ko si ọkọ ati omi lawọn ọrọ to n tẹnu awọn panapana naa jade nigba tawọn eeyan pe wọn lori ọrọ ina naa.
Ọkunrin ṣọrọṣọrọ ọhun bẹ ijọba ki wọn dide iranlọwọ fun oun atawọn yooku to fara gba ninu iṣẹlẹ naa.