Ijamba mọto gbẹmi eeyan meji loju ọna Gbọngan si Ifẹ

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Eeyan meji lo gbẹmii mi ninu ijamba ọkọ kan to ṣẹlẹ laaarọ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, loju ọna Gbọngan si Ifẹ, nipinlẹ Ọṣun.

Gẹgẹ bi Alukoro ajọ ẹṣọ oju popo nipinlẹ Ọṣun, Agnes Ogungbemi, ṣe sọ, aago mẹta idaji ọjọ Iṣẹgun nijamba naa ṣẹlẹ laarin mọto meji, Toyota Camry kan to ni nọmba FKJ 746 DU lo fori sọ bọọsi Hiace kan to ni nọmba FKJ 634 XW.

Eeyan mẹtalelogun lo wa ninu awọn ọkọ naa, loju ẹsẹ lawọn meji jade laye, nigba ti ọpọ fara pa.

Ogungbemi ṣalaye pe ileewosan Obafemi Awolowo University Teaching Hospital ni wọn ko awọn ti wọn fara pa lọ fun itọju, nigba ti awọn ẹru ti wọn ba ninu mọto mejeeji wa ni agọ ọlọpaa to wa niluu Ipetumodu.

O waa rọ awọn onimọto lati tubọ kiyesara si i, paapaa, lasiko ọdun yii.

 

Leave a Reply