Ijamba mọto paayan mẹta l’Olowotẹdo

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Ni nnkan bii aago mẹrin irọlẹ kọja iṣẹju meje, ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹfa, oṣu kọkanla yii, ni ijamba mọto kan waye l’Olowotẹdo, loju ọna marosẹ Eko s’Ibadan, eeyan mẹta si doloogbe loju ẹsẹ.

Awọn tiṣẹlẹ naa ṣoju wọn ṣalaye, pe ọkọ Toyota Camry kan ti ko ni nọmba idanimọ lo da wahala naa silẹ.

Wọn ni mọto ọhun lo fẹẹ sare ya tirela to ko igo ofifo ọti silẹ, nibi to si ti n fagidi ṣe bẹẹ ni dẹrẹba to wa tirela naa ti padanu ijanu ọkọ, bi tirela ṣe lọọ kọ lu Sienna to wa niwaju ẹ niyẹn, o si paayan mẹta ninu awọn marun-un to wa ninu ọkọ naa.

Alukoro TRACE, Babatunde Akinbiyi, naa fidi eyi mulẹ. O ṣalaye pe awọn meji kan naa fara pa, awọn mẹta si ku loju-ẹsẹ.

Mọto Camry to da ijamba  ọhun silẹ ko duro gẹgẹ bi Alukoro ṣe wi, niṣe lo sa lọ raurau ti ẹnikẹni ko ri i mu, bẹẹ ko ni nọmba ti wọn le fi tọpasẹ rẹ.

Ni ti Sienna teeyan ku ninu rẹ yii, nọmba tiẹ ni SHS 31 XH. Tirela to kọ lu u ni nọmba tiẹ jẹ AKD 361 XY. Teṣan ọlọpaa Ridiimu ni wọn ko awọn mejeeji lọ.

Nigba to n ba ẹbi awọn to padanu ẹmi wọn yii kẹdun, Akinbiyi sọ pe ile igbokuu-si aladaani kan to wa ni Ṣagamu loku awọn eeyan wọn wa, awọn si ko awọn to fara pa lọ sileewosan Famobis, to wa ni Lotto.

Bakan naa lo kilọ fawọn awakọ ti wọn n fi tiwọn ko ba ara yooku yii, o ni ki wọn ṣọ ọ ṣe loju popo.

 

Leave a Reply