Ọkunrin kan niwadii ti fidi rẹ mulẹ bayii pe o gbẹmi mi ninu ijamba ọkọ kan to ṣẹlẹ niluu Olootu-Agbe, nitosi Ikeji Arakeji, nipinlẹ Ọṣun.
Ni nnkan bii aago kan kọja iṣẹju mẹwaa ọsan Ọjọbọ, Tọsidee, la gbọ pe iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ. Ọkọ Toyota Sienna kan to ni nọmba EKY 482 GG ati ọkọ akoyọyọ (Truck) kan to ni nọmba BDG 123 XA ni wọn jọ sẹri mọ ara wọn.
Alukoro ileeṣẹ ajọ ẹsọ ojuupopo l’Ọṣun, Agnes Ogungbemi to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ sọ pe eeyan mẹfa; ọkunrin marun-un ati obinrin kan, ni wọn wa ninu awọn mọto mejeeji.
O ni loju ẹsẹ ni ọkunrin kan ku nibẹ, awọn ọlọpaa atawọn oṣiṣẹ O’Ambulance si ti gbe ẹni to ku atawọn ti wọn fara pa lọ sileewosan Wesley Guild Hospital, niluu Ileṣa.