Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Oluwoo ti ilu Iwo, Ọba Abdulrosheed Adewale Akanbi, ti ki aarẹ orileede Naijiria tuntun, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, ku oriire ijawe olubori rẹ.
Ọba Akanbi ṣapejuwe bi Tinubu ṣe jawe olubori ninu ibo naa gẹgẹ bii iṣẹgun nla fun ilẹ Yoruba. O ni ireti awọn eeyan lọdun 1993 lo ṣẹṣẹ pada wa simuṣẹ yii nipasẹ ẹni to kajuẹ ti iran Yoruba gbe kalẹ.
O ni manigbagbe ni ohun to ṣẹlẹ yii jẹ nilẹ Yoruba, paapaa, pẹlu bi yoo ṣe bu ororo itura si oju ọgbẹ ti iran naa gba lọdun 1963 ati 1993.
Oluwoo sọ siwaju pe inu oun dun pupọ fun ọrọ idupẹ ti aarẹ tuntun naa sọ pẹlu bo ṣe ṣẹleri lati sin awọn ọmọ orileede yii.
O waa ke si Aṣiwaju Bọla Tinubu lati nawọ ifẹ si gbogbo awọn ti wọn jọ dupo patapata, o si rọ awọn araalu lati fọwọsowọpọ pẹlu ijọba rẹ.
Ọba Akanbi gbadura fun ọgbọn, imọ ati idari fun Tinubu nipasẹ eyi ti ireti awọn araalu ko fi ni i ja sofo, ti Naijiria yoo si fi ṣe rere labẹ iṣejọba rẹ.