Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Kọmisanna feto iroyin ati ilanilọyẹ nipinlẹ Ọṣun, Funkẹ Ẹgbẹmọde ti ṣekilọ pe oju ọta aabo nijọba yoo fi wo ẹnikẹni ti ko ba lo ibomu, iru ijiya to ba si tọ si i naa ni yoo gba.
Ninu atẹjade kan ti kọmisanna ọhun fi sita nirọlẹ ọjọ Aje, Mọnde, lo ti ṣalaye pe pẹlu irọkẹkẹ wahala ajakalẹ arun Korona ẹlẹẹkeji yii, o pọn dandan ki olori di ori rẹ mu.
O ni gbogbo awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun ni wọn gbọdọ mọ pe awọn ko gbọdọ tura silẹ rara, gbogbo ilana to yẹ lati tẹle to wa nilẹ nipa idena arun naa lonikaluku gbọdọ pada si i ṣe bayii.
Ẹgbẹmọde fi kun ọrọ rẹ pe fifọ ọwọ pẹlu ọṣẹ, lilo sanitaisa, lilo ibomu, jijinna sira ẹni ati imọtoto agbegbe ti pọn dandan bayii, ijọba ko si ni i fi ọwọ yẹpẹrẹ mu ẹnikẹni to ba ṣe lodi si awọn nnkan yii.
O ni gbogbo ẹnuubode to wọle sipinlẹ Ọṣun lo ti wa ni ṣiṣi, awọn eeyan n wọle, bẹẹ ni wọn n jade, lai mọ ẹni to ti lugbadi arun naa, idi si niyi ti onikaluku fi gbọdọ ṣọra gidigidi, ki wọn si ti ijọba lẹyin ninu ipa to n sa lati dena arun naa.