Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ karun-un, oṣu Kẹfa, ọdun 2023 yii, ni gbogbo ọmọ ijọ Katoliiki nipinlẹ Ondo ṣeranti awọn ẹgbẹ wọn bii mọkanlelogoji ti wọn ku, atawọn ti wọn fara gbọta lasiko tawọn agbebọn kan lọọ ka awọn olujọsin ọhun mọnu ṣọọṣi Francis Mimọ, to wa laduugbo Ọwaluwa, niluu Ọwọ, lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ karun-un, oṣu Kẹfa, ọdun 2022.
Ni ibamu pẹlu atẹjade kan ti Akọwe iroyin ijọ Katoliiki nipinlẹ Ondo, Ẹni-ọwọ Ikwu Augustine fi sita, o ni odidi ọsẹ kan gbako ni ayẹyẹ iranti naa yoo fi waye, eyi ti yoo bẹrẹ lọjọ Aje, Mọnde ọjọ karun-un, oṣu Kẹfa.
Lara awọn eto to ni awọn ti la kalẹ fun ọsẹ iranti ọhun ni titan abẹla kaakiri ilu, eto isin fun yíya ijọ ati pẹpẹ ijọ ti iṣẹlẹ ọhun ti waye si mimọ ati ṣiṣe aṣekagba rẹ pẹlu eto isin nla ni iranti awọn akọni wọn to ba iṣẹlẹ buruku naa rin.
Eto isin gbogbogboo, ṣiṣi ibudo ti ijọba ipinlẹ Ondo kọ fun iranti awọn to fara gba ninu iṣẹlẹ naa ati abẹla titan yipo ilu Ọwọ ni tọjọ Aje, Mọnde, ọjọ karun-un.
Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹfa, ni wọn ṣeto lati ṣabẹwo si ẹbi awọn to ku atawọn to fara pa. Sọọsi ati pẹpẹ yiya si mimọ ni ti Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹjọ, ti wọn yoo si ṣe aṣekagba eto ọhun lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹwaa, oṣu kẹfa, pẹlu isin iranti fun awọn to ku atawọn to fara gbọta, eyi ti yoo waye ninu ṣọọṣi Francis Mimọ.
ALAROYE gbọ pe ọjọ Aje, Mọnde, lo yẹ ki Aarẹ orilẹ-ede yii tuntun, Bọla Ahmed Tinubu, wa si ibudo iranti ti wọn kọ ọhun, ṣugbọn lojiji ni iroyin mi-in tun jade pe Aarẹ ko ni i le wa mọ, nitori awọn akanṣe iṣẹ kan to wa lọwọ rẹ.