Ijọba ṣafikun rẹpẹtẹ si owo-oṣu Aarẹ, gomina, atawọn oloṣelu gbogbo

Faith Adebọla

 Ibuwọlu Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu nikan ṣoṣo lo ku bayii, ibuwọlu naa lo n da eto afikun rẹpẹtẹ kan ti ijọba to wa lode yii gun le lati ṣe si owo-oṣu awọn oloṣelu, bẹrẹ latori owo-oṣu Aarẹ, igbakeji rẹ, awọn gomina atawọn igbakeji wọn gbogbo, awọn aṣofin, awọn adajọ ati gbogbo awọn amugbalẹgbẹẹ wọn yika-yika.

Ẹka ileeṣẹ ijọba to n ri si ọrọ ipawo-wọle, inawo, ati eto iṣuna, The Revenue Mobilisation, Allocation and Fiscal Commission (RMAFC) lo sọrọ yii di mimọ l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹfa ta a wa yii.

Alaga ileeṣẹ RMAFC, Muhammadu Shehu, ẹni ti kọmiṣanna apapọ kan, Abilekọ Rakiya Tanko-Ayuba, ṣoju fun ṣiṣọ loju afikun gọbọi ọhun lasiko to n ṣalaye eto ẹkunwo-oṣu naa fun Gomina ipinlẹ Kebbi, Alaaji Dokita Nasir Idris, lọfiisi rẹ.

Wọn ni ileeṣẹ naa ti pari eto, wọn si ti ṣafikun ilọpo meji o le mẹrinla, iyẹn (114 per cent) si iye tawọn oloṣelu tọrọ yii kan n gba lọwọlọwọ bayii.

Alaga naa sọ pe labẹ isọri kẹrinlelọgọrin (84) ati isọri ikẹrinlelọgọfa (124) iwe ofin ilẹ wa, ileeṣẹ naa laṣẹ, o si lẹtọọ, lati pinnu iye owo-oṣu ti Aarẹ, igbakeji aarẹ, awọn gomina, igbakeji gomina, awọn minisita, awọn kọmiṣanna, awọn olubadamọran pataki, awọn aṣofin gbogbo, titi kan awọn adajọ atawọn mi-in ti wọn dipo oṣelu kan tabi omi-in mu yoo maa gba nigbakuugba.

O lo ti di ọdun mẹrindinlogun sẹyin tawọn ti ṣafikun owo-oṣu awọn eeyan wọnyi sẹyin, o si ti waa pọn dandan bayii lati ṣatunyẹwo owo-oṣu wọn ọhun, kawọn tun ṣafikun rẹ, nibaamu pẹlu nnkan ti ọrọ-aje orileede yii n sọ, ati bi ọwọngogo ọja ṣe wa latari yiyọ tijọba yọwọ kilanko wọn lori afikun owo-ori epo bẹntiroolu.

O ni tori kawọn araalu atawọn tọrọ kan le sọ erongba wọn jade lori afikun tawọn gun le yii lawọn ṣe ṣe apero itagbangba lawọn ilu nla-nla kaakiri ẹkun mẹfẹẹfa ti orileede wa pin si lọjọ Wẹsidee, ọjọ kin-in-ni, oṣu Keji, ọdun yii, tori awọn ko fẹ kọrọ naa da bii pe niṣe lawọn da a ṣe, tabi pe niṣe lawọn lọọ ṣe e ni kọrọ.

Abarebabọ apero ọhun lawọn fi foju ṣunnukun wo gbogbo ẹ, tawọn si dori ipinnu lati ṣẹkuwo si owo-oṣu naa, gẹgẹ bo ṣe ṣalaye.

Pẹlu eto yii, bi aarẹ ba buwọ lu u, ohun ti eyi tumọ si ni pe owo-oṣu aarẹ yoo fo fẹrẹ lati miliọnu mẹta aabọ Naira loṣu kan si miliọnu mẹjọ Naira loṣooṣu. Iru afikun onilọpo-ilọpo yii kan naa ni yoo si de ba owo-oṣu awọn yooku ti eto naa yoo kan gbogbo.

Leave a Reply