Faith Adebọla, Eko
Ijọba ipinlẹ Eko ti fofin de aṣa ṣiṣẹ oku lọjọ sinu ile adani tawọn eleebo n pe ni ẹnbaamu (embalment) ati titọju oku pamọ sile bayii, wọn lẹnikẹni ko gbọdọ tun ṣe iru nnkan bẹẹ mọ jake-jado ipinlẹ naa.
Atẹjade kan ti Akọwe agba lẹka to n ri si atunṣe ofin (Lagos State Law Reform Commission), Abilekọ Ade Adeyẹmọ, buwọ lu, sọ pe tori ewu ajakalẹ arun nijọba ṣe ṣofin yii.
O ni latilẹ wa, ko bofin mu lati sọ yara adani ninu ile tawọn eeyan n gbe di ibi igbokuu-pamọ-si, tabi ki wọn maa da kẹmika si oku lara nibẹ lati ṣe e lọjọ, ko si yẹ ki wọn sọ ile gbigbe di itẹkuu. Awọn ọsibitu ijọba ati aladaani to ni aaye fun iru nnkan bẹẹ ti wa kaakiri to yẹ kawọn eeyan maa lo gẹgẹ bo ṣe sọ.
O fi kun un pe bijọba ko ṣe sọrọ lori ọrọ yii tẹlẹ ko tumọ si pe aṣa naa bofin mu, ati pe loorekoore lawọn maa n yiri awọn ofin ipinlẹ Eko wo lati mu un ba igba mu, lara ẹ si ni ofin ti wọn kede yii.
Ni ipari ọrọ rẹ, Adeyẹmọ ni ta a ba fẹẹ bọ lọwọ ewu akoran ati ajakalẹ arun bii Ẹbola, iba Lassa atawọn mi-in, o pọn dandan ka pa ofin yii mọ, tori ẹnikẹni to ba tapa si i lati asiko yii lọ yoo geka abamọ jẹ niwaju adajọ.