Ọlawale Ajao, Ajao, Ibadan
Ààrẹ orile-ede yii, Ọgagun Muhammadu Buhari, ti fọwọ si idasilẹ ile-ẹkọ gbogboniṣe si ipinlẹ Ọyọ.
Akọwe agba nileeṣẹ to n mokuto eto ẹkọ labẹ ijọba apapọ orileede yii, Ọgbẹni sonny S.T. Echono, lo fìdí iroyin yii múlẹ nínú lẹta to fi kede igbesẹ naa fún Ẹnjinnia Ṣẹyin Makinde ti i ṣe gomina ipinlẹ Ọyọ.
Ilu Ayédé, la gbọ pe ile-ẹkọ gíga ọhun yóò wa. Ileewe poli akọkọ jake-jado ipinlẹ Ọyọ yii ni wọn yóò kọ sí ilu Ayédé, nijọba ibilẹ Ogo-Oluwa, ni ipinlẹ naa.
Gẹgẹ bo ṣe wa nínú lẹta naa, “Ijọba apapọ ti pese biliọnu meji naira nipasẹ TETFUND (ajọ tó n gbọ bukaata eto ẹkọ nilẹ yii) lati fi bẹrẹ sí í kọ ileewe naa.
“Laipẹ yii nigbimọ tó n ṣakoso eto ẹkọ gíga nilẹ yii yóò waa ṣabẹwo si ipinlẹ Ọyọ lati yẹ ibi tẹ ẹ ti pese silẹ fun ileewe yẹn l’Ayede, ka lè mọ bóyá eto ẹkọ máa lé bẹrẹ níbẹ titi inu oṣù kẹwàá, ọdun 2021 yii.”