Ijọba apapọ fofin de ṣiṣe fiimu ti awọn oṣere ti n ṣoogun owo nibẹ sita

Ijba apap fofin de ṣiṣe fiimu ti awn oere ti n oogun owo nib sita

Adewale Adeoye

Ni bayii, o ti deewọ fawọn oṣere ori itage ati ti tiata, yala lede oyinbo ni tabi ti Yoruba, koda, ko yọ ede Ibo silẹ, lati maa ṣe fiimu ti wọn ti n ṣafihan bi wọn ṣe n ṣoogun owo tabi mu siga nibẹ sita mọ. Wọn ni oṣere to ba lu ofin naa ninu fiimu to ba gbe jade maa jiyan rẹ niṣu ni.

Alakooso ajọ  to n mojuto ṣiṣe fiimu sita lorileede yii ‘The National Film And Video Censor Board’ (NFVCB) Ọgbẹni Shaibu Husseini lo sọrọ ọhun di mimọ l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kejilelogun, oṣu yii, lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ niluu Enugu, lẹyin ipade pataki kan to waye laarin ajọ NFVCB atawọn oṣere tiata lorileede yii .

Ninu ọrọ rẹ, Husseini ni, ‘’A ti n de ibi to daa ninu fiimu ṣiṣe lorileede yii, igbesẹ gidi la si ti n gbe bayii, igbesẹ to maa so eeso rere si i lori fiimu ṣiṣe sita lorileede yii, o si tun jẹ igbesẹ to maa ran awọn obi, alagbatọ atawọn araalu lọwọ gidi ni.

‘‘Nigba ti alakooso ajọ NFVCB to jẹ ṣaaju mi kọkọ fọrọ ọhun to Alhaji Lai Mohammed ti i ṣe minisita fun eto iroyin, ọrọ aṣa ati iṣe leti lati fopin si bawọn oṣere tiata kọọkan ṣe n mu siga ninu fiimu, o ni o yẹ ki wọn tun fofin de ṣiṣe fiimu ti wọn n ṣoogun owo atawọn ohun ti ko bojumu rara ninu awo ere ti wọn n gbe jade yii.

Loni-in, inu mi dun gidi lati sọ fun yin pe minisita eto iroyin, aṣa ati iṣe lorileede yii, Abilekọ Hannatu Musawa, ti ṣamulo ẹsẹ ofin kan to gbe ṣiṣe fiimu sita lorileede yii, minisita ọhun si ti fọwọ si fifi ofin de ṣiṣe fiimu ti wọn n mu siga, fiimu ti awọn oṣere tiata ti n ṣoogun owo nibẹ, atawọn ohun ti ko bojumu rara sita bayii. Bakan naa la si ti fọrọ ọhun to ẹka ileese eto idajọ orileede yii leti, awọn paapaa ti ni ẹda iwe ọhun ti minisita ti fọwọ si lọwọ bayii, fun idi eyi, o ti waa deewọ fawọn oṣere tiata lorileede yii lati maa ṣe awọn fiimu to lodi sofin naa jade.

‘ ‘O ṣe pataki pupọ fun wa lati maa sọ iru ewu to wa nidii bawọn oṣere tiata lorileede yii ṣe n ṣe awọn fiimu ti ko daa, tawọn ọmọde si n wo nigba gbogbo sita. Fun apẹẹrẹ, awọn fiimu tawọn oṣere tiata n ṣe ti wọn n mu siga nibẹ, ẹkọ gidi wo lawọn ọdọ orileede yii fẹẹ kọ nibẹ, akoba nla lo maa fa fun wọn bi wọn ba wo o tan.

‘‘A ko fara mọ ṣiṣe awọn fiimu ti ko daa sita mọ, o ti deewẹ fawọn oṣere tiata lorileede yii lati maa mu siga ninu fiimu ti wọn ba n ṣe fawọn araalu, ipalara gidi niru ere bẹẹ maa n jẹ fawọn ọdọ atawọn ọmọde lawujọ wa.

Awọn gbajumọ oeṣre tiata, ogbontarigi adari fiimu atawọn ilu mọ-ọn-ka oṣere jake-jado orileede yii ni wọn peju-pesẹ sibi ipade pataki ọhun.

Leave a Reply