Ijọba apapọ kede ọjọ Aje gẹgẹ bii isinmi lẹnu iṣẹ

Adewale Adeoye

Bi ohun gbogbo ba lọ bo ṣe yẹ, ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu, Karun-un, ọdun 2023 yii, ni wọn yoo bura fun aarẹ tuntun ti wọn dibyan lorileede yii. Eyi lo mu ki awọn alaṣẹ ijọba apapọ ilẹ wa kede ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun yii gẹgẹ bii isinmi lẹnu iṣẹ. Wọn ni eyi yoo fun awọn eeyan lanfaani lati fara mọ awọn ẹbi wọn nile, ki wọn si tun maa wo gbogbo bi eto ibura sipo fun aarẹ tuntun ilẹ wa yoo ṣe waye lori tẹlifiṣana wọn lọjọ naa.

Akọwe agba fun minisita eto ọrọ abẹle lorileede yii, Dọkita Shuaib Belgore, lo fi atẹjade ọhun sita loruko Rauf Aregbeṣọla l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹẹdọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun 2023 yii.

 Aregbesola gba awọn araalu nimọran pe ki wọn yago fohun to le da wahala silẹ lakooko ti wọn fi wa ninu isinmi ọhun, ki wọn si maa ṣohun to le mu ki ẹmi ijọba dẹmokiresi ilẹ wa gun si i.

Aregbesola ni, ‘Mo n fi akoko yii rọ gbogbo awọn ọmọ orileede yii pata pe ki wọn lo akoko isinmi tawọn alaṣẹ ijọba apapọ ilẹ yii fun wọn lati fi ṣohun to le mu ilọsiwaju ba orileede yii lapapọ, ko sohun to da bi ijọba dẹmokiresi ta a n lo lọwọ yii rara. 

Leave a Reply