Faith Adebọla
Aarẹ Muhammadu Buhari ti kede pe ọfẹ lawọn arinrin-ajo yoo wọ reluwee ni gbogbo asiko ọdun Keresi titi lọọ denu ọdun tuntun, bẹrẹ lati ọjọ kẹrinlelogun, oṣu kejila, ọdun 2021, si ọjọ kẹrin, oṣu ki-in-ni, ọdun 2022.
Ijọba ni eto naa jẹ lati mu kara tu awọn araalu to maa rin irinajo lati ipinlẹ kan si omi-in lasiko pọpọṣinṣin ọdun, ki wọn le fara rora pẹlu awọn mọlẹbi ati ololufẹ wọn.
Ọga agba ileeṣẹ reluwee ilẹ wa (Nigeria Railway Corporation), Ọgbẹni Fidet Okhiria, lo kede ọrọ yii l’Abuja, ninu atẹjade kan to fi lede lorukọ Aarẹ Buhari lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kerinlelogun, oṣu yii.
Atẹjade naa ka lapa kan pe: “Ijọba apapọ ti Aarẹ Muhammadu Buhari n dari ti ṣeto pe ọfẹ ni reluwee yoo maa gbe awọn ero lati ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kejila, si ọjọ kẹrin, oṣu Kin-in-ni, ọdun 2022.
“Eyi jẹ lati mu ki ara tu awọn araalu tori owo ọkọ to gara kaakiri orileede yii, wọn aa si le lọ kaakiri ibi to wu wọn lati gbadun pọpọṣinṣin ọdun.
“Amọ ṣa o, awọn ero ni lati gba tikẹẹti ti wọn maa fi wọle lawọn ibudokọ to yẹ, wọn o si gbọdọ sanwo, ọfẹ ni.
“Bakan naa lawọn ero gbọdọ pa alakalẹ ati ilana to rọ mọ itankalẹ arun Korona mọ, ki wọn wọ ibomu wọn, ki wọn fọwọ, ki wọn si maa lo sanitaisa loorekoore.”
O nijọba ti ṣeto fun aabo to peye ati awọn agbofinro lati fi awọn arinrin-ajo lọkan balẹ bi wọn ti n lọ ti wọn bọ.