Monisọla Saka
Igbimọ ileeṣẹ ijọba apapọ, Federal Executive Council (FEC), ti ṣofin pe ede abinibi ni ki awọn olukọ ileewe alakọọbẹrẹ jake-jado orilẹ-ede Naijiria fi maa kọ awọn ọmọ lagbegbe koowa wọn.
L’Ọjọruu, Wẹsidee, ọgbọnjọ, oṣu Kọkanla, ọdun yii, ni wọn fi ofin naa lelẹ nibi ipade ti wọn ṣe pẹlu Aarẹ nile ijọba orilẹ-ede yii niluu Abuja.
Minisita feto ẹkọ, Mallam Adamu Adamu, to sọ eleyii di mimọ lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ ṣalaye pe loootọ ni ijọba mọ pe, iṣamulo ofin tuntun naa yoo nira, ṣugbọn ile-ẹkọ alakọọbẹrẹ nikan ni wọn ti maa kọkọ bẹrẹ na, ati pe lẹyin iwe mẹfa, ede Gẹẹsi ati ede abinibi agbegbe kọọkan ni wọn yoo maa papọ fi kọ awọn ileewe sẹkọndiri kekere.
O ni, “Igbesẹ tuntun yii ti bẹrẹ, o si ti fẹsẹ mulẹ bayii, ṣugbọn o digba ti ijọba ba pese awọn ohun eelo ikẹkọọ to yẹ, ti wọn si wa awọn akọṣẹmọṣẹ olukọ to poju owo ki iṣẹ too bẹrẹ ni pẹrẹu lori ẹ.
Nitori pe oriṣiiriṣii nnkan ni ilẹ Naijiria ti padanu pẹlu awọn ede ilẹ wa kan to ti wọgbo, idi rẹ niyi ti ijọba ṣe gbe igbesẹ yii lati daabo bo aṣa wa, ki wọn si ta ede ati aṣa to n ku lọ ji”.
Adamu tun ṣalaye siwaju si i pe, niwọn igba to ti jẹ pe ede abinibi ilẹ Naijiria le ni ẹgbẹta, ede adugbo ati agbegbe kaluku ni yoo duro bii ede abinibi ti wọn yoo fi maa k’ọmọ. O fi kun un pe, ede kan ko ju ọkan lọ, bakan naa si lo ri niwaju ijọba.
O ni, “Awọn igbimọ ileeṣẹ ijọba apapọ ti buwọ lu iwe ofin naa. Ni bayii, ilẹ Naijiria ti ni aṣẹ tuntun ti wọn yoo maa ṣamulo lori eto ikọni, laipẹ yii si ni ileeṣẹ tọrọ kan yoo sọrọ le e lori.
‘‘Lati oni yii lọ ni aṣẹ naa ti bẹrẹ, ti iṣẹ si gbọdọ bẹrẹ lori ẹ, ṣugbọn a nilo asiko diẹ lati ṣeto awọn ohun eelo to yẹ ati awọn olukọ ti wọn yoo maa kọ awọn ọmọ bakan naa. Nigba to si tun ti jẹ pe ede abinibi la ni ki wọn fi kọ awọn ọmọ lọdun mẹfa akọkọ wọn nileewe, ede ti wọn ba n sọ lagbegbe ibi ti wọn wa ni wọn yoo lo”.
Adamu ṣalaye siwaju si i pe erongba ijọba lori ofin tuntun yii ni lati ṣe igbelarugẹ fawọn ede ilẹ Naijiria, ati pe ileeṣẹ eto ẹkọ yoo ṣalaye ni ẹkunrẹrẹ lori eto naa laipẹ.