Ijọba Buhari fẹẹ sọ ifẹyinti awọn olukọ di ogoji ọdun lẹnu iṣẹ

Nibi ipade awọn ọmọ igbimọ ti wọn n ba Aarẹ Muhammadu Buhari ṣepade ni wọn ti fọwọ si i bayii pe ni kete ti olukọ lawọn ileewe ijọba ba ti pe ẹni ọdun marundinlaaadọrin ni wọn gbọdọ maa fẹyin wọn ti.

Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, ni ipinnu ọhun waye nibi ipade ọ̀hún, eyi ti Ààrẹ Muhammadu Buhari funra ẹ wa nibi ipade ọhun niluu Abuja.

Lori iwe abadofin ti wọn sọrọ le lori yii ni wọn tun ti jiroro nipa ifẹyinti awọn olukọ lẹnu iṣẹ kuro ni ọgọta (60) ọdun si ọdun marundinlaaadọrin (65). Bakan naa ni wọn tun jiroro lori bi awọn tiṣa yoo ṣe maa lo ogoji (40) ọdun lẹnu iṣẹ dipo ọdun marundinlogoji (35).

Nibi ipade tawọn Buhari ṣe yii naa ni wọn ti bu ọwọ lu u, bẹẹ ni minisita feto ẹkọ, Adamu Adamu, ti ba awọn akọroyin sọrọ lori igbesẹ tuntun yii ni kete ti wọn pari ipade ọhun.

Ni bayii ti wọn ti fẹnuko le e lori, ile-igbimọ aṣofin agba ni lati fọwọ si i, nibi ti wọn yoo ti bu ọwọ lu u, ti yoo si dofin.

 

Leave a Reply