“Lọjọ ti mo ti gbọnju, emi o ri igba kankan ni orilẹ-ede wa yii ti awọn Ọmọ Naijiria pin si yẹlẹyẹlẹ bayii, ti awọn ẹya gbogbo n di ọta ara wọn. Asiko ijọba ti a ni yii ni iru ẹ n ṣẹlẹ, ohun ti gbogbo wa si gbọdọ moju to ko too di ohun ti yoo fọ Naijiria patapata ni!” Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ lo n ṣe bayii sọrọ nibi ipade awọn agbaagba orilẹ-ede yii kan niluu Abuja, ni Ọjobọ, Tọsidee, ana yii.
Ẹni to ti fi igba kan jẹ olori ilẹ wa yii sọ pe gbogbo ikunsinu ati ede-aiyede laarin ẹya gbogbo ni Naijiria to ti n di ohun igbagbe ni bii ọdun mẹwaa sẹyin, gbogob ẹ ni ijọba yii ti fi àìlákiyèsí ati eto wúruwùru ji dide pada, ti kinni naa si n le ju bo ti wa tẹlẹ lọ. “Nidii eyi”, gẹgẹ bi Ọbasanjọ ti wi, “eto ọrọ aje wa ko dara, eto aabo ilẹ wa ko sunwọn, ohun amayedẹrun gbogbo n bajẹ, debii pe Naijiria ti fẹẹ di ọkan ninu awọn orilẹ-ede to ja kulẹ lagbaaye, ati orilẹ-ede ti ọrọ wọn da bii ti afapẹ̀rẹ̀-pọnmi, awọn aláṣedànù lasan!”
Nibi ipade Abuja ti Ọbasanjọ ti n sọro yii, oju pe ẹsẹ pele ni, nitori awọn aṣoju ẹgbẹ Afẹnifẹre wa nibẹ, bẹe lawọn aṣaaju Ijaw lati Naija-Dẹlita, bẹẹ lawọn ẹgbẹ agbaagba ilẹ Ibo ti wọn n pe ni Ohaneze, awọn ẹgbẹ aagbaaga ilẹ Hausa, ati awọn aṣoju lati aarin-gbungbun Naijiria (Middle Belt). Nibi yii ni Ọbasanjọ ti sọ pe eyi ti ijọba Buhari da silẹ ninu ọrọ yii ni i jẹ oun, nitori lati igba ti wọn ti de yii, gbogbo awọn ohun ti wọn ti fi ọgbọn lẹ pọ tẹlẹ lawọn bẹrẹ si i tuka: ti wọn fẹẹ mọ ohun to n sọrọ ninu redio; bẹẹ ẹni to ba fẹẹ mọ ohun to n sọro ninu redio yoo ba iṣẹ oyinbo jẹ ni.
Ọbasanjo ni ohun to fa a ti gbogbo ẹya fi n pe awọn fẹe ṣe tawọn lọtọ, awọn ko ṣe Naijiria mọ, bayii ni iwa ailododo, aiṣe-deede ati iwa ẹlẹyamẹya laarin awọn ti wọn n ṣejọba, pe ti Naijiria ba ri bo ti yẹ ko ri ni, ko ni i si ẹya kan ti yoo sọ pe oun n lọ sibi kan. Idi ni pe ko si ibi ti a le gba sa funra wa, nitori koda ki a ma jọ jẹ ọmọ orilẹ-ede kan naa mọ, aladuugbo ara wa ni a oo ṣi maa jẹ titi aye, ẹni kan ko saa ni i fi adugbo tirẹ silẹ fẹni kan. O ni ki ijọba Buhari tete yi nnkan pada, ki wọn ma jẹ ki Naijiria fọ mọ wọn lori o.
Ododo ọrọ l’Ọbasanjọ sọ yẹn. Ọnà abayọ lo ku
Oro gidi ni baba so
Ko si ironibe . Ki Olorun ki ofun wa in adari rere
Ki olorun gba wa lowo ijoba afebi pani