Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti
Ijọba ipinlẹ Ekiti ati agbarijọpọ ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ti fẹnu ko lori owo oṣu tuntun fun ipele keje si ikẹtala gẹgẹ bi ijororo to ti n lọ tẹlẹ.
Lalẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee ana, ni wọn tọwọ bọ iwe adehun naa, eyi to wa fun awọn oṣiṣẹ nileeṣẹ ijọba gbogbo, kansu ijọba ibilẹ, awọn oṣiṣẹ eto idajọ ati ti eto ilera.
Ninu adehun naa ni wọn ti sọ pe awọn oṣiṣẹ onipele keje si ikẹtala yoo bẹrẹ si i gba afikun owo oṣu tijọba fọwọ si tẹlẹ loṣu yii, gẹgẹ bi wọn ṣe bẹrẹ si i san an fun ipele kin-in-ni si ikẹfa lọdun to kọja. Bakan naa ni wọn fẹnu ko pe ipele kẹtala si ikẹtadinlogun yoo jẹ anfaani ọhun lẹyin ti igbimọ to jẹ akojọpọ awọn aṣoju ẹgbẹ oṣiṣẹ ati tijọba ba ṣeto to yẹ.
Ijokoo naa tun pinnu pe ijọba ko gbọdọ fiya jẹ oṣiṣẹ kankan to lọwọ si akitiyan lati ṣe afikun owo oṣu ọhun nitori ipa ti wọn ko, bẹẹ ni wọn ko gbọdọ yọ ẹnikẹni niṣẹ nitori ọrọ naa.
Olori oṣiṣẹ, Abilekọ Peju Babafẹmi, pẹlu amugbalẹgbẹẹ gomina lori ọrọ oṣiṣẹ, Comrade Oluyẹmi Ẹsan ati olori ẹka idasilẹ iṣẹ, Ọgbẹni Bayọ Ọpẹyẹmi ni wọn fọwọ si iwe adehun naa lorukọ ijọba, nigba ti alaga igbimọ asọyepọ naa, Comrade Kọlapọ Fatomiluyi pẹlu awọn alaga ati akọwe ẹgbẹ NLC ati TUC fọwọ si i lorukọ awọn oṣiṣẹ.
Ninu ọrọ ẹ, Anilekọ Babafẹmi fidi ẹ mulẹ pe ipinlẹ Ekiti ni awọn oṣiṣẹ to kunju oṣuwọn ti wọn si n ṣiṣẹ takuntakun, nigba ti Comrade Fatomiluyi ni awọn nigbagbọ pe Gomina Kayọde Fayẹmi yoo ṣe awọn nnkan tawọn fọwọ si.