Ijọba Eko bẹrẹ ayẹwo fawọn to n lọ silẹ Mẹka

Adewale Adeoye

Bi gbogbo nnkan ba lọ bo ṣe yẹ, ọjọ Aje. Monde, ọjọ kẹjọ, oṣu Karun-un, ọdun 2023 yii, ni awọn alaṣẹ ijọba Eko yoo bẹrẹ si i ṣayẹwo fawọn to n lọ silẹ Mẹka lọfẹẹ, ti eto ayẹwo ọfẹ naa yoo tun pari lọjọ kẹrindinlogun, oṣu yii kan naa.

Atẹjade kan latọdọ ajọ to n ri si lilọ silẹ mimọ nipinlẹ Eko, to fidi ọrọ ọhun mulẹ sọ pe gẹgẹ bii iṣe awọn, o ṣe pataki fawọn ti wọn ba n lọ silẹ mimọ naa lati kọkọ ṣayẹwọ fun wọn, ki wọn le mọ iru ipo ti ilera wọn wa ko too di pe wọn gbera lọ sorileede Saudi Arabia lọhun-un, nibi ti eto naa ti maa n waye lọdọọdun fawọn ẹlẹsin Musulumi gbogbo jake-jado agbaye.

Alukoro ajọ naa, Ọgbẹni Saheed Onipede, ni ki i ṣẹ iṣe kekere rara lawọn to maa n lọ silẹ mimọ naa maa n ṣe ni gbogbo akoko ti wọn ba fi wa lọhun-un yẹn, idi to fi ṣe pataki fawọn paapaa lati mọ iru ipo ti ilera wọn wa ko too di pe wọn gbera rara nile lati lọọ pari iṣẹ opo karun-un ẹsin Islam, gẹgẹ bi Ọlọrun ti ṣe pa a laṣe fawọn ẹni to ba lowo lọwọ ninu wọn ree.

O ni, ‘Iṣẹ Hajji ki i ṣiṣẹ kekere rara, ọpọlọpọ wahala ati idaamu ni wọn n lọọ ṣe nibẹ ni gbogbo akooko ti wọn ba maa fi wa nibẹ, eto ayẹwo ọfẹ naa ṣe pataki, yoo jẹ ki kaluku wọn mọ iru aisan tabi arun to wa lagọọ ara wọn, tawọn dọkita ogbontarigi gbogbo tijọba Eko ti pese silẹ yoo si ri i daju pe wọn ṣetọju wọn daadaa ki wọn too gbera nilẹ yii lọọ soke okun.

O ni awọn eto ayẹwo ọfẹ naa yoo maa bẹrẹ ni aago mẹjọ owurọ kutu ni gbogbo ọjọ lawọn mọṣalaṣi to wa ni ọfiisi ijọba atijọ ‘ Old Secretariat’, GRA, niluu Ikeja, nipinlẹ Eko.

Awọn to n lọ lati agbegbe bii: Agege, Amuwo-Odọfin ati Ikeja ni wọn yoo kọkọ bẹrẹ eto ayẹwo ọfẹ to bẹrẹ lọjọ Aje naa fun, nigba tawọn agbegbe bii: Ajerọmi-Ifẹlodun, Mushin, Shomolu ati Suurulere maa ṣe tiwọn lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii kan naa. Awọn agbegbe bii: Alimosho, Kosọfẹ ati Ifakọ-Ijaye maa ṣe tiwọn lọjọ to tẹle e.

Leave a Reply