Aderounmu Kazeem
O kere tan, ṣọọbu to fẹẹ tó ọtalelugba(260)ni ijọba Eko sọ pe oun yoo wo danu lagbegbe Fagba, lojuna Oko Ọba, lẹyin ikilọ ọjọ meje to fun awọn to ni wọn bayii.
Opin ọsẹ yii ni ileeṣẹ ijọba to n ri si amojuto ayika sọrọ yii.
Alaga ajọ naa, Ọlayinka Ẹgbẹyẹmi, sọ pe awọn ṣọọbu ati ile tawọn eeyan kan kọ sẹgbẹẹ titi lawọn ti lẹ iwe mọ pe ki wọn ko wọn kuro laarin ọjọ meje.
O fi kun un pe awọn ṣọọbu ati ile ti wọn kọ yii lawọn janduku maa n sun sinu ẹ, ati pe pupọ ninu wọn ni wọn lọwọ sí wahala to ṣẹlẹ l’agbegbe Oko Ọba ati Fagba, lasiko rogbodiyan iwọde SARS, ti wọn si ba ọpọ dukia jẹ.
“Wahala nla lawọn janduku yii da silẹ ni agbegbe yẹn lasiko rogbodiyan iwọde ta ko SARS, bẹẹ lawọn olugbe agbegbe Fagba ko le foju kan oorun.
“Lara awọn ibi ti Gomina Babajide Sanwo-Olu ati kọmiṣanna ọlọpaa ṣabẹwo si, Fagba wa ninu wọn. Ohun ti wọn si sọ ni pe pupọ ninu awọn janduku ti wọn lọwọ ninu ija to ṣẹlẹ l’agbegbe yẹn, awọn ọmọọta to n gbe inu ṣọọbu ti wọn kọ kaakiri lo fa a.”
Ẹgbẹyẹmi lo sọ ọ.
O ni ọga ọlọpaa Eko ti paṣẹ pe lẹyin ọjọ meje tawọn fun kaluku ki wọn fi palẹ ẹru wọn mọ, niṣe nijọba yoo wo gbogbo ṣọọbu ati ile tawọn ti fa ila si pe kí wọn ko kuro yii.