Adewale Adeoye
Nitori bawọn ileejọsin kan, atawọn ile igbafẹ mi-in ṣe n fariwo buruku tiwọn di awọn araalu yooku lọwọ, ijọba ipinlẹ Eko ti lọ kaakiri ipinlẹ naa, wọn si ti awọn ṣọọṣi atawọn ile itaja igbalode ti wọn jẹbi ẹsun ti wọn fi kan wọn pa.
Ọjọ Iṣẹgun Tusidee, ọjọ karun-un, oṣu Kọkanla, ọdun yii ni awọn oṣiṣẹ ajọ amunifọba tipinlẹ Eko, yi to jẹ ẹka ileeṣẹ ijọba to n ri sọrọ ayika lọ sawọn agbegbe bii: Ogudu, Gbagada, Iyana Ejigbo, Isọlọ, Ajao Estate, Oṣodi, Ilasamaja ati Ọkọta, nipinlẹ Eko, ti wọn si ti awọn ṣọọṣi kan, ile itaja igbalode atawọn ile igbafẹ gbogbo ti wọn n fi ariwo buruku tiwọn di awọn araalu lọwọ.
Kọmiṣana ọrọ ayika nipinlẹ Eko, Ọgbẹni Tokunbọ Wahab, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹfa, oṣu Kọkanla, ọdun yii, sọ pe awọn oṣisẹ ajọ kan ti wọn n pe ni, ‘Lagos State Environmental Protection Agency (LASEPA) ni wọn lọ kaakiri ipinlẹ Eko, ti wọn si fọwọ ofin mu awọn araalu ti ko gbọran sofin ipinlẹ naa.
Lara awọn ṣọọṣi ti wọn ti pa patapata nitori ti wọn n fi ariwo tiwọn di araalu lọwọ ni ‘The Redeemed Christian Church of God’ (RCCG), Celestial Church of God, ile igbafẹ OMA Night Club And Lounge, Lounge And Lodging, Bridge Spot Bar, Okiki Event Center And Hall, Emota Paradise Hotel Phase 2, CF Hotel And Suite, House 27 Hotel and Suite, Echo Spring Hotel ati Smile T Continental Hotel and Suite.
Kọmiṣanna ọhun ni o wa ninu iwe ofin ipinlẹ Eko pe ẹnikankan ko gbọdọ fi ariwo tiẹ di awọn araalu yooku lọwọ rara, ati pe ijiya nla lo wa fẹni to ba ṣe bẹẹ labẹ ofin.
O ni o ṣe pataki pupọ fawọn lati maa fọwọ ofin mu awọn aleti lapa ti wọn fẹẹ maa kọ eti ikun si ofin ayika nipinlẹ Eko, ko le jẹ ẹkọ nla fawọn araalu yooku pe iwa palapala ko daa.